Lọjọ Abamẹta {Satide} ọsẹ to kọja yi ni Gomina ipinlẹ Ekiti, Ọmọwe Kayọde Fayẹmi lọ sibi ayẹyẹ igbeyawo ọmọ Gomina ana nipinlẹ naa, Oloye Ayọdele Peter Fayọṣe, eyi to waye nipinlẹ Ekoo.
Latigba ti fọto awọn oloṣelu meji naa tọpọ awọn ọmọ Naijiria n ri gẹgẹ bi ata ati oju nidi oṣelu ti bẹrẹ sii sọ oriṣiriṣi nipa awọn mejeeji, nitori pe ko sẹni to le nigbagbọ wipe eto tabi ayẹyẹ kankan yoo tun pa awọn mejeeji papọ.
Ko si nnkan meji to fa a, bi ko ṣe ti ohun to ṣẹlẹ lọdun to kọja nibi idibo to waye nipinlẹ Ekiti, ti Fayọṣe fẹsun oriṣiriṣi kan Gomina Fayẹmi wipe ṣe ni Aarẹ Buhari ati ẹgbẹ oṣelu APC pawọpọ pẹluu ajọ INEC lati yi ibo fun un.
Pẹluu idunnu ati ayọ lawọn mejeeji fi pade ara wọn lọjọ naa, to si n ṣe ọpọ awọn eeyan ni kayeefi wipe awọn mejeeji tawọn eeyan ri gẹgẹ ọta yi tun le rẹrin sira wọn.
Fun awọn ọdọ ti wọn n ṣeku pa ara wọn lori awọn oloṣelu yoowu nitori apoti ibo, tabi ipo kan, asiko re e lati mọ wipe ko si oloṣelu kankan lorilẹ-ede Naijiria gbọdọ tori ẹ ku. Inu idunnu ati ayọ lọpọ awọn oloṣelu Naijiria n wa wipe awọn eeyan n ku nitori wọn.
Ẹ jẹ ka ronu gidi.
No comments:
Post a Comment