ETO IṢUNA ỌDUN 2020: Ẹ WAA GBỌ NNKAN TI GOMINA DAPỌ ABIỌDUN TUN SỌ O - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, November 25, 2019

ETO IṢUNA ỌDUN 2020: Ẹ WAA GBỌ NNKAN TI GOMINA DAPỌ ABIỌDUN TUN SỌ O

Loni tii ṣe ọjọ Aje (Mọnde) ni Gomina ipinlẹ Ogun, Ọmọba Dapọ Abiọdun tun sọ ọrọ, to si ya gbogbo awọn ọmọ ati olugbe ipinlẹ naa lẹnu wipe ko si iṣẹ akanṣe asan kankan ti yoo jẹwyọ ninu eto iṣuna ọdun to n bọ, iyẹn ọdun 2020.

Gomina Abiọdun sọrọ naa nibi eto ipade eto iṣuna ọdun 2020 to waye ni gbọngan awọn Ọba Alaye (Oba's Complex) to wa ni Oke-Mọsan niluu Abẹokuta, nibẹ lo si tun ti sọ pe awọn ti pa gbogbo nnkan ti wọn fẹẹ ṣe lọdun 2020 papọ soju kan lati gbe e lọ sile igbimọ aṣofin, ki wọn le bu ọwọ luu lẹyin agbeyẹwo wọn.


Bakan naa lo tun sọ nibẹ wipe gbogbo awọn iṣẹ akanṣe karimi lati fi kowo jẹ, eyi to pe ni White Elephant Project lawọn yoo mu kuro patapata, ati pe awọn nnkan tawọn araalu n fẹ ni yoo di ṣiṣẹ ṣiṣẹ patapata.

Gomina Abiọdun sọ pe ojuṣe ijọba ti kọja ki wọn maa fi awọn ẹtọ araalu bọ awọn to wa nipo agbara, nitori naa awọn gbọdọ lo awọn owo ẹtọ (allocation) to n wọle sibi to ba yẹ, tori pe ayabara ni oṣelu jẹ
  
Bakan naa lo gbawọn oṣiṣẹ ijọba lamọnran wipe ki wọn fọwọsowọpọ pẹluu oun lti ri i wipe awọn owo to n wọle naa lọ sawọn ibi to ba yẹ, ki wọn si fi ṣe awọn iṣẹ to ba yẹ, eyi ti yoo ṣe gbogbo araalu lanfaani.








No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI