Lọ́jọ́ Iṣẹgun (Tusidee) àná ni ẹgbẹ́ akọroyin nipinlẹ Ondo fi aami ẹyẹ oriyin dá Gómìnà ipinlẹ náà, Arakunrin Oluwarotimi Akeredolu lọla fún tí àwọn iṣẹ́ àkànṣe manigbagbe tó ń ṣe káàkiri gbogbo origun ipinlẹ náà.
Ẹgbẹ́ náà tí Kọmureedi Adetọ̀na Aderoboye jẹ́ alaga wọn gbé oṣuba káre fún Gomina Akeredolu lórí àwọn ìdàgbàsókè ailẹgbẹ, pàápàá nípa ti eto ọ̀rọ̀ ajé.
Aderoboye nígbà tó ń ṣàpèjúwe àwọn ìdàgbàsókè tí Gomina Akeredolu tí mú wọ ipinlẹ náà láti bí ọdún mélòó kan sẹ́yìn, Ó ní kó tíì sí gómìnà tó ṣì ṣe irú ẹ, pàápàá làwọn ẹ̀ka bíi ìlera, eto ẹ̀kọ́, iṣẹ àgbẹ̀, omi àti òpópónà tó já geere.
Nínú ọ̀rọ̀ Gomina Akeredolu lọ tí sọ pé lára àwọn ìlérí tòun kò gbọ́dọ̀ má mú ṣẹ làwọn nnkan táwọn èèyàn ti ń rí náà, tò sì lòun yóò sá gbogbo agbára àti ipa òun láti tẹ síwájú.
No comments:
Post a Comment