EDGAL IMOHIMI, KỌMIṢANA ỌLỌPAA TUNTUN BẸRẸ IṢẸ NIPINLẸ OGUN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, November 18, 2019

EDGAL IMOHIMI, KỌMIṢANA ỌLỌPAA TUNTUN BẸRẸ IṢẸ NIPINLẸ OGUN

Bi ẹ ṣe n ka iroyin yi lọwọ, Kọmiṣana ọlọpaa tuntun nni, Edgal Oluwọle Imohimi ti sọ pe iṣẹ ti bẹrẹ ni pẹrẹu bayii lati maa gbogun ti iwa ọdaran, ibajẹ atawọn oniruuru iwa ti ko ba ofin mu.

Gẹgẹ bi alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa, Abimbọla Oyeyẹmi ṣe fi to AWIKONKO leti laipẹ yi.

Bẹ o ba gbagbe, lọsẹ to kọja ni ileeṣẹ ọlọpaa lorilẹ-ede Naijiria ṣe atunto kaakiri awọn ipinlẹ meloo kan, eyi ti ipinlẹ Ogun ati Ekoo naa si wa lara wọn.

A gbọ pe ni nnkan bi aago mọkanla owuro oni tii ṣe Aje (Mọnde) ni Edgal Oluwọle Imohimi wọle sinu ọgba olu ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ naa, eyi to wa ni Elewran niluu Abẹokuta pẹluu awọn ikọ akọwọrin ẹ ti igbakeji ọlọpaa, Edward A Ajogun lewaju wọn.


Ninu ọrọ akọkọ ti a gbọ pe Edgal Imohimi kọkọ ni bo ṣe sọ ki gbogbo awọn ọlọpaa patapata nipinlẹ naa pada si ẹnu iṣẹ wọn, nitori pe awọn fẹẹ mọ iye ti gbogbo ọlọpaa to wa labẹ oun jẹ.

Bakan naa lo tun fofin de gbogbo awọn ti wọn ti lọ fun isinmi pada sẹnu iṣẹ wọn, ati pe ki gbogbo awọn to n gbero lati lọ fun isinmi ranpẹ ṣi gbe e ti sẹgbẹ kan naa fungba diẹ toun yoo pari nnkan toun fẹẹ ṣe.

Nibẹ lo ti sọ pe iṣẹ ti bẹrẹ ni pẹrẹu lati kapa gbogbo awọn oniṣẹ ibi lasiko ti ayẹyẹ ọdun ti n wọle de bayii.

Bẹẹ lo ṣeleri wipe oun yoo tubọ gbaruku ti eto aabo nipa gbigbe ọlọpaa agbegbe (Community Policing) larugẹ, lati rii pe iwa ọdaran lọ sopin igbagbe.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI