ÈDÈ ÀTI ÀṢÀ YORÙBÁ: ÀWỌN AKẸ́KỌ̀Ọ́ MAPOLY GBỌ̀NÀ ÀRÀ YỌ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, November 23, 2019

ÈDÈ ÀTI ÀṢÀ YORÙBÁ: ÀWỌN AKẸ́KỌ̀Ọ́ MAPOLY GBỌ̀NÀ ÀRÀ YỌ


Ọjọ́ manigbagbe lọ́jọ́ Ẹtì (Furaide) àná jẹ fún gbogbo àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ilé ẹ̀kọ́ gbogbonìṣe tí Moshood Abiola tó wà lágbègbè Òjérè nílùú Abẹ́òkúta, ipinlẹ Ògùn lórí bí wọn ṣe fakọyọ fún tí ìgbélárugẹ àṣà àti èdè Yorùbá.
Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí wọn wá ní ipele kinni in (ND 1) lẹ́ka iṣẹ́ ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ àti ìkànsíra-ẹni (Mass Communications) là gbọ́ pé wọn fi ẹ̀bùn wọn hàn nípa ìgbélárugẹ ẹ̀kọ́ èdè àti àṣà ìbílẹ̀ tí wọn ń kọ.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ipele ipele ni àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà pín ara wọn sí láti figagbaga laarin ara wọn, kí wọn sì mú àwọn tó peregedé julọ, síbẹ̀ wọn ní ètò náà ṣì ń tẹ síwájú lọ́jọ́ Ẹtì tó ń bọ̀. 

Alakoso ẹ̀kọ́ èdè Yorùbá, Ọgbẹni Ismail Babalọla tó tún jẹ oga agba ìwé ìròyìn AWIKONKO sọ pé dandan ni ka máa gbé àṣà àti èdè abinibi wá lárugẹ, èyí tó jẹ́ ìdí tí wọn ṣe ṣagbekalẹ eto naa fún àwọn ògo Yoruba láti mọ rírí nnkan àjogúnbá wọn. 


Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ naa fakọyọ dáadáa, tí wọn sì mú orí olùkọ́ wọn wù lórí ọ̀nà tí wọn gba láti fi ajulọ hàn ara wọn. 

Díẹ̀ re ẹ lára bí eto naa ṣe lọ si:
 
 













No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI