Ẹ GBỌ NNKAN TI ỌBASANJỌ SỌ LORI ILEEPO TUNTUN, 'COMMANDER' TI WỌN ṢI NILUU ABẸOKUTA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, November 20, 2019

Ẹ GBỌ NNKAN TI ỌBASANJỌ SỌ LORI ILEEPO TUNTUN, 'COMMANDER' TI WỌN ṢI NILUU ABẸOKUTA

Aarẹ tẹlẹri lorilẹ-ede Naijiria, Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ ti sọ pe lara awọn nnkan to tubọ n mu itẹsiwaju ati idagbasoke ba orilẹ-ede Naijiria ni bawọn ọjọgbọn ṣe n kopa ninu ọrọ epo rọbii, nitori pe ipa ti wọn n ko ko kere rara.

Oloye Ọbasanjọ lo sọrọ naa lonii nibi ayẹyẹ ti ifilọlẹ ileepo tuntun ti wọn pe orukọ ẹ ni Kọmanda, eyi to wa lagbegbe Oke-Ibukun, Aṣero niluu Abẹokuta.

Nibẹ lo ti sọ pe ipa ti idasilẹ awọn ileepo n ko lorilẹ-ede Naijiria ko ṣe e fọwọ rọ ti sẹyin nipa idagbasoke, to si jẹ pe lara rẹ ni ipese iṣẹ fawọn ọdọ.

Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ ti agbẹnusọ rẹ, Oloye Abraham Idowu Akanle ṣoju fun sọ pe lara awọn to fi ara wọn jin si iṣẹ epo rọbii ni Oloye Oyebọla to jẹ oludasilẹ ileepo Commander naa.

Bakan naa lo tun sọ pe ileepo tuntun naa yoo tun jẹ afikun si eto ọrọ aje agbegbe naa nitori pe wọn yo gbawọn eeyan siṣẹ, ati pe awọn atẹgun ni ileepo naa jẹ fun eyi to tun n bọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI