Igbakeji Gomina nipinlẹ Ogun, Oniọ-ẹrọ Nọimọt Salakọ-Oyedele ti pariwo sita fawọn obinrin wipe ki wọn fara jin fun oṣelu dipo ko jẹ wipe ẹgbẹjọda nikan ni wọn yoo gbajumọ, nitori pe ọna kan ṣoṣo ti wọn le fi da si nnkan to n lọ lorilẹ-ede yi niyẹn.
Onimọ-ẹrọ Salakọ-Oyedele lo sọrọ naa nibi eto ọlọdọọdun ti ẹgbẹ Trade Union Congress of Nigeria (TUC), ẹka tawọn obinrin to waye ninu gbọgan ẹgbẹ ASUSS to wa ni Lẹmẹ niluu Abẹokuta.
Nibẹ lo ti sọ pe awọn obinrin ni opo to di awujọ mu, to si pọn dandan fun wọn lati kopa ninu oṣelu ati ijọba, ati pe ijọba to wa nita lasiko yi, iyẹn ijọba Dapọ Abiọdun fi faaye sile fun wọn lati da si eto iṣejọba.
Salakọ-Oyedele ni, ijọba yi mu ọrọ awọn oṣiṣẹ abẹ rẹ lokunkundun, to si jẹ ẹ logun gidigidi, eyi to kun fawọn olukọni atawọn oṣiṣẹ ijọba, to si jẹ pe obinrin lo pọ ju laarin wọn, to si pọn dandan lati maa da owo oṣu lasiko.
No comments:
Post a Comment