Kani kii se opelope awon eleyinju aanu ti won tete ranse pe awon olopaa ni, o see se kawon araadugbo ti lu iyaale ile kan tojo ori e ko tii ju odun mejidinlogun lo, Busayo Ayeni pa latari esun ti won fi kan an wipe o fi majele pa oko re to bimo meta fun.
Adugbo kan ti won n pe ni Anobe to wa lagbegbe Aregbe, Obantoko niluu Abeokuta nisele naa ti waye lojo keedogun oṣù kewaa, iyen ni nnkan bi aago mejo aabo aaro.
Gege bi iroyin to te AWIKONKO lowo se fi ye wa, won ni oro oyun ti Busola ti won lo n kiri ounje bii Eba, Amala ta kaakiri igboro ni fun ale re lo da wahala sile laarin oun ati oko re, Tunde Ayeni, omodun marundinlogogji toun yan ise weda (welder) laayo.
Omo adugbo Ijemo niluu Abeokuta ni won pe Mama to bi Tunde, nigba ti won so pe Baba re je omo Kotonu (Republic of Benin). Odun mejo seyin la gbo pe Tunde ati Busola fe ara won, ti won si pada bimo meta funra won, bo tile je pe won ni eyokan ni omo Tunde ninu awon omo meta yii.
Awon to fisele naa to wa leti je ko ye wa pe o ti pe ti Busayo ati ale re naa to da wahala yi sile yi, eni ti a ko tii moruko re dasiko ti asakojopo iroyin yi tan ti n fe ara won. Won ni opo igba ni Busola maa n fi foonu Tunde pe ale re bi ko ba ti lowo lori foonu tie, iyen lasiko ti Tunde ti won tun n pe ni Baba Esther ko ba si nibe.
Sugbon nigba ti asiri maa tu sita, won ni osu meta seyin ni asiri tu si Tunde lowo pe Busola n fi obe eyin je oun nisu, ti won si ni Busayo so fun un ki eni naa kii se ale oun, alaanu oun lasan lo je, ko si si nnkan to pa won po. Won loju ese ni Tunde ti loo fejo sun awon eeyan Busayo, sugbon ti won so pe ko gbo si won lenu.
A gbo pe opo igba ni Busayo maa n dagbere fun oko re pe oun n lo sodo egbon re kan, sugbon ti won ni kii debe, to si je pe ile ale re ni yoo lo. Eyi ni won so pe won fa titi tasiri tun fi tu si Tunde lowo pe oun ko loun loyun osu marun to wa ninu iyawo oun, to si ranse pe iya ati egbon re lati wa a gbo sisele naa, sugbon ti won pada bawon yanju e.
Nigba tisele buruku naa maa waye, a gbo pe ale ojo Monde ni Busayo fi majele sinu ounje to gbe fun Tunde lero wi pe bi yoo ba fi maa di osan ojo keji, majele naa yoo bere ise, sugbon ti won so pe aarin feere ojo Tuside ni majele naa bere ise.
Won nigba ti Busayo rii pe majele naa ti bere ise, lo bas are gbe Tunde, to si loo juu sinu salanga kan ti ko si nnkankan nibe, eyi to wa legbe ile won, toun ko too di pe o sa jade kuro nile, ki asiri ma baa tu.
A gbo pe awon kan ti won n duro de Tunde ni won n pe fonu e titi, sugbon ti ko seni to gbe, eni naa ni won loo wa Tunde wa sile, to si je pe nigba to maa de egbe ile won tawon eeyan n gba koja, niyen kofiri Tunde ninu koto naa, to si pariwo sita fawon ara adugbo.
Loju ese ni won ti pe Busayo lati fi too leti, sugbon ti leyin bi wakati meji lo too de be leyin ti won gbe Tunde jade. Won ni Tunde ti n po foomu lenu nigba ti won fi maa gbe e jade, eyi lo mu ki won sare da omi lee lori, ti won si gbe e lo si osibitu lati doola emi e.
Osibitu ti won koko gbe Tunde de lawon ko le gba a , idi ni yii ti won fi gbe e lo si osibitu min in, sugbon ti epa ko pada boro nigba ti won maa gbe e debe, awon osise osibitu naa ni won sakiyesi pe majele to je lo seku paa, ti won si gbe ku e pada sile.
Awon ti won mo bo se n lo laarin Tunde ati Busayo daadaa ladugbo la gbo pe won kona iya fun Busayo pe ko jewo nnkan to fi pa oko re, ti won si ni ko jewo, koda ti won ni ko baraje pe oko oun ti ku.
Okan lara awon egbon Tunde, to je aburo mama e nigba to n b’AWIKONKO soro so pe “Lojo ti n maa gbo si oro naa, Tunde lo pe mi pe ki n maa sare bo, tori pe wahala maa sele. O ni mama oun ko ni je koun se nnkan to wa ninu oun. Ki n to debe lojo yen Busola ti sa jade nile nigba to gbo pe mo n bo.
“Tunde ni ki n woo ori foonu oun pe Busola ti n yan ale. Ati pe ale naa ma n wa wa sile. Ibe lo tun ti pe ale naa loju mi. Ale yen n so fun Tunde pe nnkan ti Busola so foun ni pe omo kan soso pere loun bi, to si tun so pe oun ko si nile oko pe oko oun ti ku.
“Mo faraya lati le Busola jade nile lojo naa, sugbon won so pe ki n fi suuru se e, wipe egbon Busola ti wa bebe. Aimoye igba lo maa fi odo mi dagbere fun oko re ti mi o si ni ri. Lojo kan lo so pe oun ti wa lona ile mi, nigba to maa de, o ti le bii wakati mefa ko too de, mo soro si, mo si ni ko pada sile. Latigba yen ko ti ma n ki mi mo.
“Nigba to maa pad aba mi soro, se lo fi foonu oko re pe mi pe oko oun ti ku ki n maa bo. Mi o koko daa lohun, se lo tun pe pada, igba to si je pe nomba oko re lo fi pe mi lo je ki n wa. Iku Tunde ko gbodo lo lasan bee, kawon omo Niajiria gba mi.”
Okan lara awon araadugbo to ni ka foruko boun lasiri to sunmo Tunde daa da so pe “Osibitu kan la koko gbe e lo, ko too di pe a gbe e lo si osibitu Zion. Ibe ni won ti yee wo pe kii se pe o fese tabi apa ro ko too jabo sinu salanga, ati pe salanga yen, bi omo to sese n ra ba ko sibe, yoo jade funra re.
“Mo ri laaro ana, awon to si ri ni ale ana ri, afigba ti won pe mi pe o ti jade laye. Ki Tunde too ku, o so fawon eeyan pe eyokan lomo toun ninu awon omo tiyawo oun bi foun, o si tun je ka mo pe oun ko loun ni oyun inu iyawo oun. Inu redio ati pepa ni mo ti n ka a, mi o mo loooto, eleyi lo je ki n mo pe aye n be loooto.”
Busayo nigba toun naa n soro, o ni “Mi o le so pe nnkan bayii lo sokunfa iku e. Laaro ana (Monde) to ji, idi aso ti mo fo lojo Sande ti mo n sa lowo lo ti wa ba mi, o ko egberun mefa naira fun mi pe ki n lo san an ninu owo ileewe awon omo wa.
“Igba ti mo pada de lawon to wa legbe soobu mi so pe oko mi ti wa, o si fi kokoro sile pe oun fee de Morekete. Eba la je lale an aka too sun. Aaro yi lo tun so pe oun n lo Morekete. Emi ati oko mi ko ja lori oro oyun. Nnkan to fa ija ti le losu meta bayii, enikan lo pe mi, to wa pe eni naa pada pe se ko mo pe ile oko ni mo wa ni.
“Iyen beere lowo e pe bawo lo se je si mi, o so fun pe oko mi lohun, ati pe omo meta la ti bi. O wa so pe emi o so bee foun. Ibi ti mo ti lo bawon ta oja la ti pade ka to maa fera wa. Laaro yi lawon kan wa kan ilekun wa wipe Tunde lawon n beere, mo ni o ti jade.
“Won ni Tunde wo lo jade, o ti wa ninu salanga. Mo pe awon eeyan pe ki won ba mi yoo, ti won si ro omi lee lori. Ibe la ti gbe e lo si osibitu. Kayeefi niku Tunde je fun mi. Mo mo pe oko mi ma n rojo kaakiri, sugbon mi o mo nnkan nipa iku e.”
Awon olopaa ni pada gbe oku naa lo si mosuari fun ayewo aridaju, ti won si mu Busayo lo si tesan won nigba tawon araadugbo fe bere sii lu. Tesan naa lo si wa dasiko ta a sakojopo iroyin yi tan.
No comments:
Post a Comment