Odu ni Arábìnrin Temitọpe Lawal Bashir jẹ́, kii ṣaimọ foloko lagboole àwọn oniroyin, pàápàá láwùjọ àwọn amuludun káàkiri orilẹ-èdè Nàìjíríà àti lagbaye.
Òní ni ayẹyẹ ọjọ́ ìbí Temitọpe Lawal, ẹni tí ọ̀pọ̀ àwọn olólùfẹ́ rẹ mọ sì Èbúté Àríyá, tó sì jẹ pe gbogbo àwọn olólùfẹ́ rẹ káàkiri àgbáyé ni wọn ti ń fi atẹjiṣẹ oríṣiríṣi ránṣẹ́ sì láti kii.
Bi wọn ba n ka àwọn akọroyin lagboole amuludun, pàápàá ni táwọn tó ń gbé èdè, àṣà àti ìṣe Yorùbá lárugẹ káàkiri orilẹ-èdè Nàìjíríà, ki wọn yóò dárúkọ márùn-ún, wọn gbọ́dọ̀ dárúkọ Temitọpe Lawal Bashir.
Kolonka làwọn aami ẹyẹ koriya tí Èbúté Àríyá tí gba lagboole amuludun, pàápàá laarin awọn akọroyin ẹgbẹ́ rẹ.
Ọkàn pàtàkì ni Èbúté Àríyá jẹ nileeṣẹ AWIKONKO MEDIA CHANNEL tó ń gbé ìròyìn AWIKONKO jáde, ìdí ni yìí tí a kò fi lè gbàgbé láti fi imọriri hàn sii fáwọn ipa tó ń ko nípa idagbasoke ileeṣẹ wá.
No comments:
Post a Comment