ÀṢÍRÍ AYÉDÈRÚ PÁSÍTỌ̀ TÓ FÓÒGÙN BA ÌYÀWÓ ONÍYÀWÓ LÁṢẸPỌ̀ TÚ L'ABẸ́ÒKÚTA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, November 23, 2019

ÀṢÍRÍ AYÉDÈRÚ PÁSÍTỌ̀ TÓ FÓÒGÙN BA ÌYÀWÓ ONÍYÀWÓ LÁṢẸPỌ̀ TÚ L'ABẸ́ÒKÚTA


BỌ̀SÚN ỌLÁNÍYÌ, ABẸ́ÒKÚTA

It is finish, it is finish, iku ya ju esin lo, e saanu mi’ loro to n jade lenu Seye Soyinka ti won pe ni pasito jade lojo Tuside, ọjọ́ kejilelogun osu kẹwàá ọdún yi niluu Abeokuta lasiko ti asiri e tu wipe o foogun ba iyaale ile kan, Kabirat Sobayo to ba iranlowo wa sodo re sun, ti ara obinrin naa ko si ya repete.

Agbegbe Itesi to wa ni Ake ni Seye ti won so pe ko ni soosi to n lo ni pato, sugbon to maa n lo kaakiri lati wa onibara re n gbe, to si tun maa n sise fawon eeyan la gbo pe opo awon obinrin paapaa iyaale ile to ba wa sodo re lo ma n muna labe won.

Gege bi a se gbo, won ni Kabirat to ti bimo marun ni ipenija lori oro aje e, ati pe apa e mejeeji tun n dun un, idi ni yi ti won loo fi lo si osibitu, to si na opolopo owo lati le je ki apa e gbadun, sugbon to je pe pabo lo ja si.

Nibi ti won lo ti n foro lo awon eyan la gbo pe won ti juwe Seye fun un wi pe o gbona nidi ise Oluwa, ati pe to ba de be, isoro re yoo dopin nipa igbagbo, tori pe opo eeyan lo ti jeri si agbara Olorun lati odo e. Idi ni yii ti won so pe Kabirat to n gbe lagbegbe Oke Aregba fi gbera lo sibe.

Lojo ti Kabirat debe ni won so pe Seye ti won ni ko ni soosi, sugbon to je pe ile e lo n lo lati dawon eeyan lohun gbe nnkan fun Kabirat je, to si tun muu lo se akanse iwe lodo, leyin ti won kuro lodo ti won ti se iwe, ti won pada dele ni Seye so pe ise ko tii pari, tori pe a fi ko pada lojo keji.

Nibe ni won loo ti so fun Kabirat pe ko mu igo oti Schnapp kan to ba n bo lojo keji. Ojo keji naa ni won so pe bi Kabirat se de lo ti gba oti naa lowo re, to si pes awon ogede kan sii, ti won loo tun nnkan sinu re, ko too gbe e fun Kabirat lati muu.

Leyin ti won ni Kabirat muu tan ni won so pe Seye tun se awon eto kan sinu koinkan (sponge) ibile meta kan wi pe oun yoo mu Kabirat de odo lati se iwe min in, ti won si niyen tele ee lo lati se iwe yi.

Ojo keta ni won ni Kabirat tun pada lo sibe lati dupe lowo e, nibe ni won so pe Seye ti foogun ba Kabirat soro wipe bi ko ba feyin lele lati baa sun, oun yoo ya a ni were, tori pe ase ti wa lenu oun, gbogbo akitiyan ti won ni Kabirat se lati ma je ki Seye baa lasepo lo ja si pabo, ti won lo si muna labe gidi lojo naa.

AWIKONKO gbo pe bi Kabirat se dele lojo naa ni oko re koluu, to si je pe ibi ti won ti n sere ife laarin oru ni oko re ti bere sii gbokiti, to si je pe ori lo koo yo, sugbon ti ara re ko tii ya titi dasiko ti a sakojopo iroyin yi tan. Bi ile se mo ni won so pe Kabirat ti bere sii fesun kan Seye lori foonu pe o ti fi nnkan ba oun sun lati pa oko oun danu.

Ibi ti won ti n soro naa lowo lo tun ti ko si Kabirat lori pe ko wa a ba oun, to si lo, to si je ko yee pe to ba fe ki oko re gbadun, afi ko di eru aye, ko si lo so o sinu odo, ti won si loun naa gba lati se. Ale ojo ti won ni Kabirat ju eru aye naa sodo peluu iranlowo Seye ni won loo la ala, to si jeun loju orun.

Bo se ji lojo keji ni won ni Asian min in tun koluu to je pe se ni inu re bere sii kun, ti nkan si n rin ninu onofun re, bee ni eti re tun n kun taitai. Eyi lo tun mu ko sare gba odo Seye lo lati loo so ija koo loju, ti won si loo tun muu lo soosi min in nibi ti won gba egberun mewaa naira lowo re.

Nigba ti Kabirat rii pe oro naa ti fee yiwo lo mu ko gba odo awon eso alaabo So Safe Corp nipinle Ogun lo lati loo foro naa to won leti, nibe ni won si ti ranse s’AWIKONKO, ta a bawon mejeeji soro.

Kabirat Sobayo ninu oro re so pe “Ore mi kan to n je Iya Dammy ni mo wa lo si Itesi to wa ni Ake, tori won so pe ibe naa ni Pasito Seye wa. Sugbon nigba ti mo de be, won I ore mi yen ko si nile, mo wa beere Pasito Seye, okunrin yi wa so fun mi pe ko si nile wipe ki lo sele, mo ni isona ati bi okoowo mi yoo se maa lo siwaju pada ni mo wa fun.

“O je ko ye mi pe aimoye awon eeyan loun ti sise fun ti aye won si ti yi pada. Nibi ti a ti n soro lobinrin kan ti pe e lori foonu, teni naa si n sepe fun, ko pe sigba naa ni omo obinrin naa wole, to wa bere sii fejo mama re sun omo naa ti won n pe ni Ayo. O je ko ye mi pe lati ojo ti eni naa ti fi olopaa mo oun ni gbogbo nnkan e ti bere sii dojuru tori pe oore loun se fun obinrin yen to tun wa n sepe bayii, nitori pe oun ko gbadura fun mo.

“Lojo yen, o ni ki n lo we lodo, wipe ti m ba ti n bo lojo keji, ki n mu oti schnapp dani. Igba ti mo debe, o fun mi lawon kankan (sponge) meta to pe ohun si pe ki n lo fi we, ti mo si loo we. Mo tun pada lo lojo keta gege bo se so pe ki n wa. Igba ti mo debe lo fun mi ni imole (candle), to si ni ki n maa lo si oke, tori pe ile alaja meji nile to n lo. Ibe lo ti so pe ki n so gbogbo nnkan ti mo fe patapata sinu imole yen, ti mo si se bee.

“O ju nnkan senu, o si n pe awon ogede kan ti mi o gbo, ibe lo ti so pe afi ki n fi eyin mi lele foun,  ti mi o ba si se bee, oun yoo ya mi ni were. Gbogbo bi mo se n bebe ni ko gbo, to so pe dandan ni, ko si bi mo se fee sa jade tori pe o ti tilekun leyin lo je ko ri aaye lati ba mi lasepo ni tipatipa, ko too se, o tun fi nkan pa ori nnkan omokunrin re lojo yen.

“Ale ojo naa ti mo dele ni oko mi ba mi sun, ibi ti a ti n sere ife lowo ni ooyi ti gbe oko mi, to si takiti kuro lori mi jabo sile, ibe ni ara ti fu mi pe Seye ti fi nkan ba mi lasepo. Olorun ni ko je ku lojo naa. Ojo keji ni mo pee lori foonu pe oun lo fi nkan ba mi sun, o tun so fun mi pe se emi ko mo pe oko mi fee fimi se nnkan ni, ati pe ori mi ni ko gbabodi.

O tun so pe ki n wa lojo kan, to loun maa di eru egbe fun mi. Igba to se bee lo mu mi lo sodo lo tuna won nnkan to maa n se. O wa ni ki n ju nnkan toun gbe fun mi saarin odo. Igba ti mo dele ni mo ala wipe won fun mi lounje loju oorun, bi mo se ji ni mo pee, to si so pe awon egbe mi lo n so mi kaakiri. Latigba naa ni nnkan ti n yi kaakiri inu ati ofun mi, ti eti tun n ro mi. Oko mi si wa lori idubule aisan, sugbon o so pe mi o gbodo pariwo oun sita.

“E ma je ki n ku bayii, omo marun lo wa nile, e saanu mi ki n ri emi toju awon omo mi tori pe mi o gbadun bi mo se n soro yi. Gbogbo ibi ti mo n de ni won nso pe won ti lo mi, ati pe ifun mi ni won lo fi se nnkan.”

Nigba toun naa n tako esun naa, Seye so pe “Lojo ti won koko wa, won ni Alagba lawon beere, mo ni se won da alagba yen mo, won lawon ko mon on tori pe won juwe foun ni, mo wa so pe Olorun ni alagba ki won jokoo. Igba ti won salaye nnkan to n se won, mo ni maa gba egberun meje aabo (7,500) naira lowo won, sugbon won be mi pe ki n gba egberun meji naira. Mo je ko ye won pe won maa se iwe, ti mo si mu won de odo nibi ti won ti we.

“Igba ti a dele, mo so fun won pe ti won ba n bo lojo keji, ki won mu igo schnapp kan dani, bo tile je pe ko si ninu ofin sele, sugbon nnkan ti mo fe ki won lo ni, Oluso Aguntan ni mi, mi o kii se Babalawo. Loooto mi o ti da soosi sile, sugbon sele ni mo ti kose. Igba ti won de, mo gba a mo si se nnkan ti mo fee se sii, mo koko muu ki n too gbe e fun won lati ri aridaju

“Leyin ti won lo kini yen tan, ni won tun pada wa, ti won wa n be mi pe ki n ba oun lasepo tori pe awon eeyan ti juwe mi foun, mo ni mi o le see, sugbon nigba ti ebe naa po, ni mo gba lati se e, mi o so pe o maa ya were dandan ti mi o ba baa sun, oun lo be mi ka too ni ibalopo.

“Looto iwa ti mo hu ko dara nitori pe mo gba lati baa lasepo si ni. Nitori irin ajo to le je ko gbadun la se lo si soosi kerubu kan lagbegbe Erunwon, ibe ni won ti jise fun un pe won maa sise kan fun, egberun mewaa naira si ni, a joo da owo yen ni. Maa se ti ara re yoo fi ya, e ma je ki oruko mi baje, e daso asiri bo mi.”

Bo tile je pe opo awon to gbo sisele yi ni won n sepe fun Seye, sibe naa ni won k obo enu lati da Kabirat lebi wipe nnkan ti oju re n wa loju re ri, ti won si n gbawon obinrin to n to awon pasito leyin lasiko yi pe ki won sora won. Gbogbo akitiyan lati ba oko Kabirat soro lo ja si pabo, nitori ti won so pe ko fe ki oro re jade sigboro aye.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI