AKẸKỌỌ UNIPORT GBE MAJELE JẸ LỌSAN GANGAN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, November 28, 2019

AKẸKỌỌ UNIPORT GBE MAJELE JẸ LỌSAN GANGAN

Iyalẹnu lọrọ iku ọdọmọkunrin kan tọjọ ori ẹ ko tii ju ọdun mẹrindinlọgbọn lọ, Prince Digbani ṣi n jẹ fawọn ọrẹ ẹ, paapaa awọn obi ẹ, lori bo ṣe gbẹmi ara rẹ sinu yara adagbe ẹ lojiji.

Akẹkọọ fasiti tipinlẹ Port Harcourt (UNIPORT) ni wọn pe Prince Digbani ti wọn lọsan gangan ọjọ Aje (Mọnde) to kọja lo fi atẹjiṣẹ ranṣẹ sawọn ọrẹ rẹ wipe ẹdun ọkan lo n jẹ foun wipe oun ko tii ṣe aṣeyọri to tẹ oun lọrun.

AWIKONKO gbọ pe fun bii ọpọlọpọ wakati ni Prince fi n powe iku sira rẹ lori ikanni ayelujara ti ibara-ẹni-sọrọ, iyẹn WhatsApp, to si n ṣe wọn ni kayeefi.

Lara awọn ọrẹ rẹ ti wọn ni ara fuu lo sare gbera lati lọ sile Prince, to si jẹ pe nigba to maa fi debẹ, ibi ti Prince ti n pokaka iku lọwọ lo wa, ti wọn si lawọn ti wọn jọ n gbe inu ile fun ni epo pupa mu lati doola ẹmi rẹ.

Nigba ti wọn ni gbogbo igbiyanju wọn fẹẹ ja si pabo lo mu ki wọn sare gbe e lọ si ọsibitu kan to wa nitosi, nibi ti wọn loo ti dagbere faye.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI