Ọrọ buruku toun tẹrin nile ẹjọ
giga to fikalẹ siluu Ilọrin nipinlẹ lọjọ Ẹti (Fraide) ọsẹ to kọja nigba ti wọn
lawọn gendunkunrin mẹrin kan ti wọn ni wọn ko niṣẹ meji ju jibiti ori
ayelujara, iyẹn Yahoo bu sẹkun lasiko ti ajọ EFCC to n gbogun ti jibiti ati
inakuna fẹsun kan wọn.
A gbọ pe ni nnkan bi ọsẹ meloo
kan sẹyin lọwọ ajọ EFCC tẹ awọn gendekunrin naa, ti wọn pe orukọ wọn ni Chilaka
Dickson, Abdulahi Abubakar, Ọlayiwọla Azeez ati Enoch Oluyọde, ti wọn si pada
foju wọn bale ẹjọ lẹyin ọpọlọpọ iwadii wọn.
Nigba ti wọn n sọrọ lori ẹsun
ti wọn fi kan wọn niwaju Onidajọ Mahmod Abdulgafar, AWIKONKO gbọ pe mẹta ninu
awọn mẹrẹẹrin lo sọ pe awọn jẹbi ẹsun ti wọn fi kan wọn, ti ọkan lara wọn si sọ
pe oun ko mọ nnkankan nipa ẹsun ti wọn fi kan oun.
Eyi lo mu ki Onidajọ Mahmood sọ
pe ki gbogbo wọnm ṣi lọ jẹgbadun diẹ lahamọ awọn EFCC, to mu ki wọn bu sẹkun pe
afaimọ kawọn ma pada ṣẹwọn.
No comments:
Post a Comment