Alaga ẹgbẹ oṣelu Mega nipinlẹ
Ogun, Alaaji Moshood Adeṣina, ti sọ pe ijọba ti Gomina Abiọdun n ṣe lọwọ nipinlẹ Ogun
yi ti wa lori ipilẹ ti ko duro daadaa latari awọn to n ko mọra, ti wọn ko si le
ran ijọba rẹ lọwọ rara, dibo bẹẹ, ipalara lo maa jẹ.
Adeṣina to tun jẹ igbakeji alaga
ẹgbẹ IPAC nipinlẹ Ogun lo sọrọ lasiko to n b’AWIKONKO sọrọ laipẹ yi niluu
Abẹokuta lẹyin ipade ti alaga ẹgbẹ oṣelu Labour, to tun jẹ alaga ẹgbẹ oṣelu
agbarijọ gbogbo awọn ẹgbẹ oṣelu nipinlẹ Ogun, Kọmureedi Abayọmi Arabambi lọọ
ṣepade pẹluu Gomina Dapọ Abiọdun nile iṣẹ ijọba to wa ni Oke-Mọsan niluu
Abẹokuta.
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, Kọmureedi
Arabambi lo ko awọn eeyan rẹ lẹyin lọọ ki Gomina Dapọ Abiọdun, nibi to ti fi
ọkan Gomina balẹ wipe digbi loun wa lẹyin rẹ, toun si ṣetan lati ran an lọwọ ni
gbogbo ọna to ba fẹ.
Ninu ọrọ Alaaji Adeṣina lo ti
sọ pe “Mi o ri nnkan to dara si ipade naa rara, idi ni pe mi o figba kan ro o
ri wipe Gomina Dapọ Abiọdun le wọ ara rẹ nilẹ to bẹẹyan, ko wa jokoo pẹluu iru
eeyan buruku alagabagebe bii Arabambi.ipinlẹ Ogun yi la wa ti Abayọmi Arabambi
fi ṣiṣẹ fun Gomina ana, Ibikunle Amosun lodi si Dapọ Abiọdun.
“Arabambi gbe Dapọ Abiọdun lọ
si ile ẹjọ Tribunal, lati ibẹ ni wọn ti gba ile ẹjọ Kotẹmilọrun, iyẹn Appeal lọ
niluu Ibadan, nibi ti ẹjó wọn ti pada fori sọgi. Awa kan wa to jẹ pe ẹgbẹ
League of Registered Political Parties la fi n ṣagbatẹru ijọba, mọkandinlogun
ni gbogbo ẹgbẹ oṣelu to parapọ lọdọ wa.
“Lasiko ti Arabambi lọ sọdọ
Dapọ Abiọdun, ibi ti a ti n ṣepade la wa lọwọ lasiko naa, to si jẹ pe Gomina
Dapọ Abiọdun la n ṣiṣẹ fun latigba ti ibo ti pari. Ti Dapọ Abiọdun ba sọ pe oun
fẹẹ gbawọn eeyan lalejo, paapaa awọn agbaagba ninu ẹgbẹ oṣelu, ko yẹ ko jẹ pe
Arabambi lo maa faaye silẹ fun lati gba lalejo. Abanijẹ lasan ni ọkunrin ti wọn
n pe ni Arabambi jẹ, oun lo si n ba ijọba Dapọ Abiọdun jẹ latigba to ti wọle.
“A gbọ pe ẹgbẹ oṣelu ọgọrin lo
ko lọ ba Gomina Abiọdun, nibo ni wọn ti ri ẹgbẹ oṣelu ọgọrin, ẹgbẹ oṣelu
mọkandinlogoji la jọ wa nibi ti a ti ṣepade lasiko toun naa wa lọdọ Gomina
Abiọdun, to si jẹ pe gbogbo wa la tọwọ bọwe pe lootọ la ṣepade. Bi ẹ lọọ wo o
daadaa, gbogbo ẹgbẹ oṣelu to wa nipinlẹ Ogun ko to ọgọta, to si jẹ pe ninu
idibo to kọja lọ, ẹgbẹ oṣelu mọkandinlogoji pere lo kopa lati fa Gomina wọn
silẹ, nibo ni wọn ti ri awọn ẹgbẹ oṣelu ọgọrin to lọ ba Gomina Abiọdun.
“Bi Gomina Abiọdun ṣe fẹẹ ṣe
ijọba ẹ lo ṣe n ṣe yẹn, o tun mọ si pe bi adigunjale gan an ba fẹẹ ri Gomina
Abiọdun, aaye ṣi silẹ, nitori pe nnkan ti gbogbo awọn to ko mọra fi n jẹun
niyẹn lati ori awọn Biyi, tori pe bi wọn ba ti gba owo lọwọ Gomina, wọn a le
gba tiwọn naa nibẹ.
“Miliọnu marun un naira ni wọn
gba lọwọ Gomina lọjọ ti wọn lọ, miliọnu meji naira ni Kọmureedi Arabambi ji ko
sapo rẹ ninu owo naa, o fawọn alaga ni ẹgbẹrun lọna aadọta naira, awọn ti wọn
kan pe lati tẹlẹ wọn, iyẹn awọn ti wọn ko mọ nnkan to n lọ gba ẹgbẹrun lọna
ọgbọn. Lẹyin eyi ni wọn tun lọọ pin miliọnu meji naira pẹluu awọn Biyi to jẹ
amugbalẹgbẹ si Gomina.
“Ẹgbẹ oṣelu Labour gan an ko mọ
pe wọn fẹẹ lọ ri Gomina, bi wọn ba fẹẹ lọ ri Gomina, gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ
gboọdọ mọ si, ṣugbọn tori ijẹkujẹ wọn, wọn ko nii ṣe e. Wọn ko pe mi gẹgẹ bi
igbakeji alaga, ibi ti a ti n ṣepade lọwọ la wa, ti a ti n gbọ.
“Bi Gomina Abiọdun ṣe fẹẹ ṣe ijọba rẹ lo ti n ṣe
yẹn, ijọba awọn abanilorukọjẹ, ijọba gbajuẹ lo n ṣe, awọn ti ko le ran ijọba ẹ
lọwọ lo fẹ maa gba mọra, nitori naa, ko si igbesẹ kankan ti a fẹẹ gbe nitori pe
igba meloo ni ọdun mẹrin yoo fi pe, a n woran bayii.”
No comments:
Post a Comment