Lọjọru Wẹside to kọja yi nile ẹjọ giga to fikalẹ siluu Enugu, nipinlẹ Enugu ju ọdọmọkunrin kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Josephat Ani sẹwọn oṣu kan gbako, bẹẹ lo tun paṣẹ pe ki wọn wọgilẹ apo ile ifowopamọ si ti Banki rẹ.
Ajọ to n gbogun ti ṣiṣe owo ilu kumọ-kumọ, iyẹn EFCC ni wọn wọ Josephat lọ siwaju Onidajọ Ibrahim Buba lori ẹsun jibiti ori ayelujara ti wọn n pe ni Yahoo-Yahoo.
A gbọ pe o ti pẹ ti Josephat ti wa nidi iṣẹ naa, to si lu ọpọ awọn oyinbo ni jibiti obitibiti owo dọla, ko da, ti wọn loo ṣẹṣẹ gba owo kan ti ko din ni ẹgbẹrun kan aabọ owo dọla ($1500) lọwọ ẹnikan to ko si i lọwọ.
Ki aṣiri Josephat too tu sita, a gbọ pe orukọ kan ti wọn pe ni General Nelson Moore ti orilẹ-ede United States, ni ẹka kan ti wọn pe ni International Leave Board, Syria Keeping lo fi n lu awọn eeyan ni jibiti.
Ọjọ keji, oṣu kẹsan an to kọja yi la gbọ pe ọwọ palaba rẹ segi, ko too di pe wọn pada foju rẹ bale ẹjọ lẹyin iwadi ati aridaju wọn.
No comments:
Post a Comment