WỌN FẸẸ ṢAYẸYẸ ISIN IDUPẸ FUN ỌNỌREBU TUNJI-OJO L'ONDO - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, October 7, 2019

WỌN FẸẸ ṢAYẸYẸ ISIN IDUPẸ FUN ỌNỌREBU TUNJI-OJO L'ONDO

Gbogbo eto lo ti fẹẹ pari bayii fun ti eto idupẹ ọlọjọ meji ti wọn fẹẹ ṣe fun Ọnọrebu Olubunmi Tunji-Ojo to n ṣoju ẹkun Akoko North-East/Akoko North-West, ipinlẹ Ondo nile igbimọ aṣoju-ṣofin niluu Abuja.

Eto naa la gbọ pe ọjọ meji gbako ni yoo fi waye, to si jẹ pe gbogbo awọn eeyan jankan-jankan atawọn oloṣelu nipinlẹ Ondo ati lorilẹ-ede Naijiria, to fi mọ Abẹnugọn ile igbimọ aṣoju-ṣofin, Ọnọrebu Fẹmi Gbajabiamila ni yoo peju sibẹ lọjọ naa.

Ọjọ Satide, ọjọ kẹrindinlọgbọn si ọjọ Sande, ọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu yi ni eto naa yoo waye lagbegbe Okeagba, to si jẹ pe ẹsẹ ko nii gbero nibẹ lọjọ naa.

A gbọ pe imọriri lawọn ọmọlẹyin Ọnọrebu Olubunmi Tunji-Ojo to tun jẹ alaga igbimọ to n ri sọrọ Niger Delta fẹẹ fi han fun un latari awọn ipa to ti ko laarin asiko ti wọn fi dibo yan an. 

AWIKONKO gbọ pe ọpọ awọn olorin ti wọn jẹ gbajugbaja ni wọn yoo dalu bọlẹ lọjọ naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI