ỌWỌ TẸ IYAALE ILE TO FẸẸ JU AWỌN ỌMỌ RẸ MEJI SINU KỌNGA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, October 4, 2019

ỌWỌ TẸ IYAALE ILE TO FẸẸ JU AWỌN ỌMỌ RẸ MEJI SINU KỌNGA

'Ẹ pami sile, ẹ daṣọ aṣiri bo mi' lọrọ ẹbẹ ti wọn lo n tẹnu iyaale ile kan ti a ko tii mọ orukọ rẹ dasiko ti a ṣakojọpọ iroyin yi tan jade nigba tọwọ tẹ lasiko to fẹẹ da awọn ọmọ rẹ meji sinu kọnga.

Adugbo kan ti wọn n pe ni Kushimọ lagbegbe Ikọtun niluu Eko niṣẹlẹ naa ti waye lọjọ Tọside ana ni nnkan bi aago mẹsan aarọ kutu.

Awọn araadugbo ti wọn ri obinrin naa atawọn ọmọ rẹ la gbọ pe wọn fura si i lori iwa to n hu lasiko to n ko awọn ọmọ naa lọ, idi ni yii ti wọn fi foju sii lara, ko too di pe aṣiri rẹ pada tu lori ipinu ẹ.

Gbogbo bi wọn ṣe sọ pe wọn n beere idi pataki to fi fẹẹ ju awọn ọmọ naa sinu kọnga la gbọ pe ko le dahun, ko too di pe wọn pada fa a le awọn agbofinro lọwọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI