ỌWỌ TẸ GBAJUMỌ ỌMỌ ẸGBẸ OKUNKUN MẸRIN L'OGIJO - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, October 14, 2019

ỌWỌ TẸ GBAJUMỌ ỌMỌ ẸGBẸ OKUNKUN MẸRIN L'OGIJO

Bi ẹ ṣe n ka iroyin, boroboro lawọn gbajugbaja ọmọ ẹgbẹ okunkun ti wọn lawọn ọlọpaa ipinlẹ Ekoo ti n wa lọjọ to ti pẹ, ṣugbọn tọwọ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti pada tẹ wọn bayii ṣi n ka nipa awọn iṣẹ buruku ti wọn ti ṣe.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, lọjọ Satide ọsẹ to kọja yi lọwọ tẹ awọn mẹrin naa, Owolabi Rasaq, ẹni ọdun mejidinọgbọn to n gbe lojule kẹta, adugbo Ibo-Igunnu, Bariga; Chidi Michael ti wọn tun n pe ni Chiboy, ọmọdun mẹrindinlọgbọn to n gbe ladugbo Adelepo, Odonla-Ikorodu; Sunday Adetiba tọpọ mọ si Sian, ọmọ ọgbọn ọdun to n gbe ladugbo Jagu Lawan, Ogijo ati Idris Jimọh, ọmọdun mẹtadinlọgbọn toun n gbe lojule kejila, adugbo Akinyemi, Liberty Estate, Itaoluwo niluu Ekoo.

Ọga ọlọpaa Ogijo la gbọ pe awọn eeyan naa ko si lọwọ lasiko ti wọn n ṣepade wọn lọwọ fun ti wahala nla ti wọn ni wọn tun fẹ lọọ da silẹ.

A gbọ pe ọpọ ẹmi awọn alaiṣẹ lawọn eeyan naa ti ran lọ sọrun aremabọ, ṣugbọn ti ọwọ palaba wọn ti pada segi bayii.

A gbọ pe Kọmiṣana ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Bashir Makama ti paṣẹ pe kiwadi tubọ tẹssiwaju lati le tete foju wọn bale ẹjọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI