ỌWỌ SIFU DIFẸNSI TẸ BAALE ILE TO FIPA JA IBALE ỌMỌDUN MẸSAN AN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, October 19, 2019

ỌWỌ SIFU DIFẸNSI TẸ BAALE ILE TO FIPA JA IBALE ỌMỌDUN MẸSAN AN

Boroboro ni ọmọ ọgbọn ọdun kan, Mohammed Babangida ti wọn fẹsun kan wi pe o fipa ja ibale ọmọdebinrin ọmọdun mẹsan an kan nipinlẹ Anambra lọhun n ka wi pe ki wọn ṣe oun jẹjẹ nitori pe iṣẹ eṣu ni.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, wọn ni owo ni Mohammed fi tan ọmọ naa, ko too fipa ja ibale rẹ lasiko tawọn obi ọmọ naa ta a forukọ bo laṣiri yi ko ba si nile.

Awọn kan ladugbo la gbọ pe wọn fura si ọmọ yi, ti wọn si ta awọn obi rẹ lolobo, lẹyin ti wọn beere oriṣiriṣi ibeere lọwọ ọmọ yi lo too sọrọ pe Mohammed ma n ba oun laṣepọ, ati pe kii ṣe ẹẹkan, idi ni yii ti wọn ṣe lọ fọrọ naa to ileeṣẹ Sifu Difensi to n sọrọ aabo ilu leti, ko too di pe wọn lọọ mu Mohammed nibi to wa.

Nigba toun funra rẹ n sọrọ, Mohammed sọ pe  "Loootọ ni mo gbiyanju lati ba ọmọ yi laṣepọ, ṣugbọn kinni mi ko tii wọnu kinni ẹ daadaa ko too dii pe aṣiri mi tu sita. Ibi ti mo ti n gbiyanju ẹ lawọn eeyan ti wọle wa a ba mi..

"Mo maa n fun ọmọ yi lowo, mo ti fun un ni aadọta ati ogun naira lẹẹmeji ọtọọtọ ri. Ẹlẹẹkẹta ti mo fun un yi ni mo gbiyanju lati ba a laṣepọ ko too di pe aṣiri tu. Ẹ ṣaanu mi, tori pe mo ni iyawo, mo si lawọn ọmọ ni Bauchi. Ẹ ma jẹ kiya jẹ mi."

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI