O MÁ ṢE Ó, TIRELA TẸ BLESSING PA, LÁSÌKÒ TÍ KẸKẸ MARUWA Ń SALỌ FÁWỌN TÓ Ń JÀ TIKẸẸTI - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, October 19, 2019

O MÁ ṢE Ó, TIRELA TẸ BLESSING PA, LÁSÌKÒ TÍ KẸKẸ MARUWA Ń SALỌ FÁWỌN TÓ Ń JÀ TIKẸẸTI


Igbe ikunlẹ abiyamọ ló gba ẹnu àwọn ará agbegbe òpópónà Ọba Owerri, ladojukọ abúlé Rojenny tó wà nipinlẹ Anambra kan lọ́jọ́ Wẹside tó kọjá yí kan nígbà tí wón ní tirela ńlá tẹ gendebinrin kan tí wọn pé orúkọ rẹ ni Blessing pa. 


Ohun tí a gbọ ni pé awakọ kẹkẹ ẹlẹsẹ mẹta kan, ìyẹn Kẹkẹ Maruwa lo dá wàhálà náà silẹ, nígbà tí wọn sọ pé ṣe ló ń sá lọ fawọn tó ń jà tikẹẹti.


Wọn ní èrè asapajude ni ẹni tó wà tirela náà ń bá a lọ, kò too di pé ẹni tó wà Maruwa náà jána mọ lẹ́nu, tó sì lọọ yiwọ mọ Blessing níbi tòun dúró sii. 


Niṣe là gbọ́ pé tirela náà tẹ kọjá sísọ, tó sì já ìfun rẹ síta. Lójú ẹsẹ̀ ni wọn loo tí sọdá sọrun alakeji. 


Kí olójú too ṣẹ, wọn ní ẹni tó wà tirela náà tí na paa bora, tí kò sì ṣeni tó mọ bó ṣe pòórá lásìkò náà.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI