Titi di asiko ti a ṣakojọpọ iroyin yi tan lawọn ikọ ẹgbẹ agbabọọlu Super Eagles ti orilẹ-ede Naijiria ṣi fi wa ninu ibanujẹ ọkan, latari bi wọn ṣe padanu ọkan lara wọn, to tun jẹ Balogun wọn, Isaac Promise.
Ọjọ Wẹside to kọja yi la gbọ pe Isaac Promise jade laye lẹni ọdun mọkanlelọgbọn (31).
Promise lo ko awọn ẹlẹgbẹ rẹ lọ sibi idije agbaye FIFA U17 to waye ni orilẹ-ede Finland lọdun 2003, bẹẹ lo tun lewaju lọ si idije agbaye ti U20 to waye lorilẹ-ede Netherlands lọdun 2005, nibi ti wọn ti ṣe ipo keji.
No comments:
Post a Comment