Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ṣeyi Makinde ti kede Ọgbẹni Bayọ Akande ati Ọgbẹni Kazeem Bọlarinwa gẹgẹ amugbalẹgbẹ ẹ lori ọrọ Boṣenlọ ati imọ ikansira-ẹni (Information Communication Technology (ICT)/E-Governance) pẹluu ọdọ ati ere idaraya.
Iṣẹ awọn meji yi la gbọ pe o ti bẹrẹ ni kete ti wọn kede ibuwọlu wọn nibamu pẹlu lẹta ti wọn fun wọn.
Ninu ọrọ ti amugbalẹgbẹ Gomina Makinde lori ọrọ iroyin, Moses Alao sọ pe kii ṣe pe wọn dee de yan awọn meji naa bi ko ṣe pe ifarajin, itẹriba ati iriri wọn nidi iṣẹ ti wọn yan laayo lo jẹ ki wọn bu ọwọ lu wọn.
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, Akande ti wọn yan gẹgẹ bi amugbalẹgbẹ lori ọrọ boṣenlọ ati eto ikansira-ẹni la gbọ pe o niwe ẹri lawọn fasiti agbaye meji ọtọọtọ, iyẹn Aston University and Sheffield.
Bakan naa ni Bọlarinwa ti wọn yan fun ipo ere idaraya atawọn ọdọ naa jẹ ọmọdun mọkandinlọgbọn naa ni iwe ẹri Master nidi ere idaraya, toun naa si tun farajin pupọ.
No comments:
Post a Comment