Ko ṣẹni to ri Baba gendebinrin arẹwa kan, Akintọla Esther Modupẹ ti wọn loo peregede julọ nile ẹkọ gbogboniṣe tiluu Ilaro, Federal Polytechnic Ilaro lasiko to n sunkun nibi ayẹyẹ ikẹkọọ jade to waye laipẹ yi, ti ko nii mọ pe ẹkun ayọ lo n sun.
Nibi eto ayẹyẹ naa to waye l'Ọjọru Wẹside ọsẹ yi, ti awọn ọba alaye bii Alaafin Ọyọ, Alake tilẹ Ẹgba, Olu Ilaro atawọn min in ti peju sibẹ ni wọn ti kede Modupẹ gẹgẹ bi akẹọọ to peregede julọ pẹluu maaki 3.90 ninu 4 ti wọn n gbe jade nile ẹkọ naa.
Gẹgẹ bi awọn ti ayẹyẹ naa ṣoju wọn ṣe ṣalaye f'AWIKONKO, wọn ni bi wọn ṣe kede gendebinrin yi lo ti fo soke, ko da, ti wọn lawọn ọrẹ rẹ tun gbe e soke ni ori awọn obi rẹ ti wọn tẹle e lọ lọjọ naa ti bẹrẹ sii wu.
Ṣe wọn ni oriire ọmọ ni idunnu obi rẹ, eyi gan an lo mu ki Baba rẹ dide lo sibi to wa, to bọ ọ lọwọ, ko da ti wọn ni iya rẹ naa dide lai di mọn ọn.
Nigba to n sọrọ, Gomina Abiọdun sọ pe iru awọn eeyan bayii yoo wulo fun ogo orilẹ-ede Naijiria, nitori naa loun yoo ṣe fun un niṣẹ lai kọ lẹta iwaṣẹ kaakiri, ati pe yoo bẹrẹ iṣẹ rẹ lẹyin to ba pari eto agunbanirọ rẹ ọlọdun kan.
A gbọ pe bi Gomina Abiọdun ṣe sọrọ yi jade, ṣe ni Baba Modupẹ dide lori ijokoo rẹ, to si kunlẹ, nibi ti omijẹ ti n jabọ rẹ wipe wahala oun lori ọmọ naa ko ja si asan, bẹẹ lo tun dupẹ lọwọ Gomina Abiọdun.
Yatọ si eyi, ṣe ni Modupẹ naa sare gba ibi ti Gomina Abiọdun wa lọ, to si lọọ kunlẹ siwaju rẹ pe oun ko le gbagbe oore nla to ṣe foun naa.
No comments:
Post a Comment