Ṣẹnkẹn bayii ninu awọn oṣiṣẹ meji nni, ti Gomina ana
nipinlẹ Ogun, Ibikunle Amosun le danu lẹnu iṣẹ lọdun bii meji sẹyin bayi n dun
latari bi Gomina Dapọ Abiọdun ṣe paṣẹ wi pe ki wọn pada sẹnu iṣẹ wọn.
Awọn eeyan naa ni Ọgbẹni Dare Ilekọya to jẹ alaga
ẹgbẹ awọn olukọ tẹlẹ nipinlẹ naa, ati Ọgbẹni Olusanjọ Majẹkodunmi, ti Gomina
Abiọdun si ti ṣeleri wi pe gbogbo ẹtọ wọn ni wọn yoo gba pada.
Gomina Abiọdun ṣeleri yi nibi ayajọ awọn Olukọ to waye ni gbagede papa iṣere MKO to wa Kutọ, niluu Abẹokuta, eyi ti wọn pe akori rẹ ni Awọn Olukọ Kekere: Ọjọ-ọla iṣẹ naa (“Young Teachers: The Future of the profession”).
No comments:
Post a Comment