EYI NI BỌWỌ ṢE TẸ ỌLAKUNLE TO JI ỌMỌ OṢU KAN GBE NI MOWE LỌJỌ SATIDE - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, October 7, 2019

EYI NI BỌWỌ ṢE TẸ ỌLAKUNLE TO JI ỌMỌ OṢU KAN GBE NI MOWE LỌJỌ SATIDE

Bo tilẹ jẹ pe ori ko baale ile ẹni ọdun mọkandinlogoji (39) kan, Ọlakunle Agbaje yọ lọwọ iku ojiji, ṣugbọn sibẹ, ko tii si aridaju wipe ko nii fẹwọn gbara, latari bọwọ palaba rẹ ṣe segi lasikoto lọọ ji ọmọ oṣu kan gbe.

Ọjọ Satide to kọja yi la gbọ pe Ọlakunle to n gbe ladugbo Dennis, Arigbabuwo niluu Owode lọ sile onile kan kan to wa lojule kejilelọgbọn, adugbo Adesan ni Mowe, ijọba ibilẹ Ọbafẹmi Owode.

Ati pe kani Ọlakunle mọ pe aṣiri oun maa pada tu sita ni, boya ko ba ti ma pinu lati ji ọmọlọmọ gbe, tori pe iya to jẹ l'ojọ naa, titi ayeraye ni yoo fi maa ranti, to si ku diẹ ki wọn dana sun un.

AWIKONKO gbọ pe oju oorun ni iya ọmọ naa wa lasiko ti Ọlakunle yọ kẹlẹkẹlẹ wọnu yara wọn, to si gbe ọmọ naa kuro lẹgbẹ rẹ, ṣugbọn tori pe ko sun asunwọra lo jẹ ko tete fura wọ ọmọ rẹ.

Iyalẹnu lo jẹ nigba to maa laju, ko ri ọmọ naa, idi ni yi to fi sare dide lati wa ọmọ naa. Bo si ṣe sare jade, kayeefi lo jẹ nigba to ri Ọlakunle lasiko to n salọ pẹlu ọmọ rẹ.

Ariwọ 'ole, ẹ ba mi mu' lo jẹ kawọn araadugbo naa dide lati wo nnkan to n ṣẹlẹ, ti wọn si pada rii pe ọmọ ni wọn jigbe, idi ni yii ti wọn fi lee mu. Nibi ti wọn ti n luu lawọn ẹlẹyinju aanu ti gbawọn nimọnran wi pe ki wọn lọọ fa a le awọn ọlọpaa lọwọ.

Agbẹnusọ fawọn ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Abimbọla Oyeyẹmi fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, o si jẹ ko ye wa pe Ọlakunle ti wa lahamọ awọn, to si n ka gbogbo ẹṣẹ rẹ sita. Bẹẹ lo jẹ ko di mimọ pe ko ni pẹẹ foju bale ẹjọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI