EYI LẸKUNRẸRẸ BAWỌN EEYAN ṢE JONA DI EERU L'ONITSHA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, October 19, 2019

EYI LẸKUNRẸRẸ BAWỌN EEYAN ṢE JONA DI EERU L'ONITSHA

Image may contain: outdoor
Ọjọ buruku, eṣu gbomimu l'Ọjọru Wẹside, iyẹn ọjọ kẹrindinlogun oṣu kẹwaa ọdun jẹ fawọn araalu Onitsha nipinlẹ Anambra jẹ, ti ọjọ naa yoo si jẹ ọjọ manigbagbe titi ayeraye, latari bi ijamba ina to fọpọ ẹmi ṣofo eyi to waye.

Titi dasiko ti ẹ n ka iroyin yi, lawọn eeyan, ẹlẹyinju aanu ṣi n fi ọrọ ibanikẹdun ranṣẹ sawọn mọlẹbi awọn to ba ijamba naa lọ, atawọn ti ori ko yọ lọjọ naa.

Image may contain: fire
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, wọn ni tanka epo bẹntiroolu kan lo n sare asapajude lọ, nigba to si maa de agbegbe tawọn eeyan pọ si, to fẹ ṣe bii pe sunkẹrẹ-fakẹrẹ ọkọ ti n ṣẹlẹ, ni wọn sọ pe awakọ naa gbe ẹsẹ le ijanu rẹ, ṣugbọn ti ko muu mọ.

Gbogbo akitiyan ti wọn sọ pe ẹni to wa tanka epo bẹntiroolu naa sa lati ma jẹ ki ijamba ṣẹlẹ ni wọn loo ja si pabo, to si mu ko ja sinu koto kan to wa lẹgbẹ opopona, iyẹn ni ibudoko MCC to wa nitosi ọsibitu Toronto, iyẹn nibi tawọn ṣọọbu oriṣiriṣi pọ si lagbegbe Upper-iweka, Onitsha.

Image may contain: one or more people, people standing and outdoor
Wọn nibẹ lo ti fẹgbẹ le lẹ, ṣugbọn to jẹ iyalẹnu wi pe ori tanka epo naa yọ sonu, toun si lọọ duro lẹgbẹ afara oloke kan to jinna.

A gbọ pe loju ẹsẹ ti tanka naa ti fẹgbẹ lelẹ ni ina ti ṣẹyọ, to si mu kawọn to wa nitosi ba ẹsẹ wọn sọrọ nigba ti ọrọ di boolọ o yago lọna.  Wọn ni awọn kan to n ta afẹfẹ idana gaasi nitosi ibẹ ni wọn sọ pe o ran ina naa lọwọ, to fi wọ awọn ṣọọbu naa.
Image may contain: one or more people and people sitting
Awọn to fiṣẹlẹ naa to wa leti jẹ ko ye wa pe ẹpa ko boro fawọn ti ko tete mọ nnkan to n lọ, to si mu ki ina naa kawọn mọ inu ṣọọbu wọn, ti wọn si jọna gburugburu.

Loju ẹsẹ la gbọ pe wọn ranṣẹ awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ panapana, ṣugbọn ti wọn lawọn yẹn sọ pe ko si omi nilẹ tawọn le lo, to si jẹ pe o ti le ni wakati meji gbako ki wọn too yọju, lẹyin tawọn ẹmi ti ṣofo danu.

Diẹ re lara awọn fọto ibi iṣẹlẹ naa:

Image may contain: one or more people and outdoor
Image may contain: outdoor
Image may contain: outdoor
Image may contain: outdoor
Image may contain: 1 person, standing and shoes
Image may contain: one or more people, people standing and outdoor
Image may contain: one or more people, people standing and outdoor
Image may contain: one or more people, people standing, cloud, sky and outdoor
Image may contain: one or more people and outdoor
Image may contain: one or more people, cloud, sky and outdoor
Image may contain: one or more people, people standing and outdoor
Image may contain: 3 people, people standing and outdoor
Image may contain: fire and outdoor
Image may contain: 1 person, standing and outdoor







No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI