Oru oni Mọnde la gbọ pe awọn oṣiṣẹ ajọ to n gbogun ti ṣiṣe owo ilu kumọ-kumọ, iyẹn EFCC yawọ ile igbafẹ kan to wa niluu Oṣogbo, ti wọn si ko obitibiti mọto ati foonu olowo iyebiye, atawọn eeyan lọ si ọgba wọn.
A gbọ pe ẹsun ti wọn fi kan awọn eeyan naa ti wọn sọ pe wọn n ṣe faaji ara wọn lọwọ ni jibiti ori ayelujara, iyẹn Yahoo-Yahoo.
Lara awọn ile igbafẹ alẹ, iyẹn Night Clubs ti a gbọ pe wọn ya wọ lọọ ko awọn eeyan ni Club Secret,
Green Arcade ati River Side.
Ko din ni mọto marundinlaadọta (45) la gbọ pe wọn ko lọ, ati kolonka fooonu. Iwadii ṣi n lọ lọwọ gẹgẹ bi a ṣe gbọ.
No comments:
Post a Comment