Ẹ GBỌ NNKAN TI ANDY RUIZ SỌ NIPA ANTHONY JOṢUA, KAYEEFI NLA GBAA NI - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, October 2, 2019

Ẹ GBỌ NNKAN TI ANDY RUIZ SỌ NIPA ANTHONY JOṢUA, KAYEEFI NLA GBAA NI

Ko sẹni to gbọ nnkan ti gbajugbaja afẹṣẹkubiojo ọmọ orilẹ-ede Mexico nni, Andy Ruiz Jr  sọ nipa afẹṣẹkubiojo ọmọ orilẹ-ede Naijiria nni, Anthony Joshua ti ko lanu silẹ fẹẹ da itọ lẹnu.

Andy Ruiz Jr sọ fun Anthony Joṣhua pe ko lọọ rọ kunle fungba diẹ naa bo ba padanu nibi idije wọn ti yoo waye lọjọ keje oṣu kejila ọdun yi ni orilẹ-ede Saudi Arabia.

O ni loootọ loun gba pe ọga Joshua nidi ẹṣẹ kikan, ṣugbọn boun ṣe fẹyin rẹ gbolẹ lọjọsi ṣi n jẹ kayeefi.

Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe "Mo lero wi pe ṣe lo yẹ ki Joshua lọ fun isinmi rampẹ ti m ba tun luu. O nilo lati gba itọju to peye ko too tun pada sori itage ẹṣẹ kikan. Ipadanu kan tabi meji ko lo le yi nnkan pada.

"Alagbara ṣi ni, afẹṣẹkubiojo to lagbara daadaa lo ṣi jẹ, o si da mi loju pe o ṣi maa duro digbi to ba ya."

Bẹ o ba gbagbe, ninu oṣu kẹfa ọdun yi ni Andy Ruiz Jr fi agba han Anthony Joshua, to si gba ipo lọwọ rẹ gẹgẹ bi alagbara.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI