Ẹ FURA O, ỌPỌ AYEDERU ỌTI BABA APARI TI WA NITA O - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, October 2, 2019

Ẹ FURA O, ỌPỌ AYEDERU ỌTI BABA APARI TI WA NITA O

Bọsun Ọlaniyi, Abẹokuta
Ko sẹni to gbọ bi baale ile ẹni ọdun marundinlaadọta (45) kan to pe ara rẹ ni Afunches Nwaha ṣe n sọrọ lọgba ọlọpaa to wa ni Eleweran niluu Abẹokuta lọsẹ to kọja yi, yoo mo pe ọdaju paraku ni, paapaa bo ṣe sọ pe ko si okoowo min in toun tun le ṣe bi ko ṣe ayederu nnkan mimu, tori pe iṣẹ toun mọ nipa ẹ daadaa ni.

Ohun ta a gbọ ni pe ọjọ Tuside ọsẹ to kọja yi laṣiri Nwaha tu niluu Agbado lẹyin ti wọn lawọn kan ti wọn fura si ọti to n ko jade ninu ile ẹ lọọ ta sita fawọn eeyan lati mu pe kii ṣe ojulowo.
Wọn loo ti le lọdun mẹrin ti Nwaha ti wa lẹnu iṣẹ yi, to si jẹ pe ko sẹni ti ko mọn ọn ni gbogbo agbegbe Agbado, ko da, ti wọn loo tun ni awọn oṣiṣẹ rẹpẹtẹ to n ba a ṣiṣẹ pọ.
Lara awọn ọti to n ṣe ayederu wọn ni Lord, Schnapps, Seaman's, Best, Seagram's Blended Whisky atawọn min in.

Lori bi asiri re se tu, a gbo pe awon kan ni won ra okan lara awon oti yi lowo e, ti won si sakiyesi pe oti naa yato si ogidi, eyi lo mu ki won loo ba a lati beere lowo e pe oti ti ojo ti lo lori e lo ta fun won.

Won ni kaka ki Nwaha farabale lati ba won soro, se lo so ija ko won loju. Idi ni yii tawon yen fi gba tesan olopaa lo lati fi to won leti, tawon yen naa si bere ise iwadii.

Nigba tasiri e maa tu, won ni ibi to ti n po awon kemika naa po lowo ni won ti ba a, ko da, ti won lo fee gba oju ferese jade ko too di pe mu oun ati okan lara awon osise e ti won pe ni Joy.

"Nigba ti won n se opopona Agbado ni won wo soobu mi ni nnkan bi odun marun seyin, ko si si nkan ti mo tun le se mo leyin ti mo ronu titi, idi ni yii ti mo fi wo o pe mo ni iriri ninu ka se oti atawon nnkan mimu, ti mo si bere e.

"Mi o gba iwe ase kankan ileese ti mo n se ayederu oti won yi, mi o si sise nibi kankan ri. Awon kan ni won maa n ko awon nnkan ti mo n lo wa fun wa. Baraaki Ojoo ni eni to n ko won wa fun mi ti n wa. Emi ni mo n po kemika po, ti maa si de e pa.
"Eni naa ti a pe ni PG lo ma n ko igo, labeeli (label) atawon paali wa fun mi. Lojo ti won maa mu mi, ibi ti mo ti n sise ni won ti wa a mu mi, iyalenu lo je fun mi nigba ti mo ri awon olopaa.

"Mo maa n se to katoonu meta lojumo. Funra mi ni mo si maa n ta a ni oja Agbado. Ojo ti n ba ta a tan ni maa tun se awon min in jade lati ta. Ibe ni mo ti n ri owo fi jeun, ti mo si n gba bukata. Mo ni awon osise, okan lara won, Joy ni owo te peluu mi.

"Kemika ati omi lasan ni mo fi n se awon oti yi. Ethanol

Joy so pe "Akoba lasan ni eleyi, tori pe mi o mo pe ayederu oti ni won n se. Igo lasan ni mo n fo, ti mo si n gba owo ise ti mo ba se. E saanu mi tori Olorun."

Komisana olopaa ipinle Ogun, Bashir Makama ti so pe afi kawon araalu sora won lati mo ibi ti won yoo ti maa ra oti won ti won n mu, nitori pe ojoojumo lowo n te awon to n se ayederu ohun jije ati mimu kaakiri.

Bee lo seleri pe awon yoo foju Nwaha bale ejo leyin tawon ba tubo pari iwadii won, nitori pe oun ko le la oju oun sile, kawon odaran maa ba oun gbe inu ipinle kan naa..

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI