BIJỌBA KO BA FỌWỌSOWỌPỌ PẸLUU AWỌN ALADANI, ỌRỌ ILEGBEE KO LE RỌRUN FAWỌN EEYAN - FAṢINA PARIWO SITA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, October 8, 2019

BIJỌBA KO BA FỌWỌSOWỌPỌ PẸLUU AWỌN ALADANI, ỌRỌ ILEGBEE KO LE RỌRUN FAWỌN EEYAN - FAṢINA PARIWO SITA

Lojuna lati le mu ki ilegbee di irọrun fawọn araalu, gbajugbaja oniṣowo nipa ọrọ ile gbigbẹ (Real Estate), Ọgbẹni Faṣina Ọlajide ti pariwo sita wi pe a fi kijọba apapọ atijọba ipinlẹ pawọpọ pẹluu awọn ileeṣẹ aladani, nitori pe oun ni yoo jẹ ọna irọrun.

Ọgbẹni Faṣina to tun jẹ alaṣẹ ati oludari ileeṣẹ Olageospatial Global Investment Company (OGIC) sọrọ naa laipẹ yi lasiko to n bawọn oniroyin sọrọ lori iṣoro to n koju awọn eeyan nipa ilegbee nibi eto ti wọn ṣe lati foju aṣoju wọn, iyẹn Ambassador han fawọn eeyan.

Nibẹ lo ti sọ pe ijọba ko le da ọrọ ilegbee awọn eeyan rẹ ṣe, lai jẹ wi pe o fọwọsowọpọ pẹluu awọn ileeṣẹ aladani to mọ nipa ilegbee atawọn to n ri ṣeranlọwọ nipa ọrọ olowo de, iyẹn private real estate developers and financial institutions.

Siwaju sii lo tun sọ pe bi ijọba ko ba tete gbe igbesẹ latari iwoye ajọ agbaye, iyẹn United Nations wi pe bi yoo ba fi di ọdun mẹwaa si asiko yi, awọn ko nii nile lori yoo tun ti le ni olọpo awọn to wa nita bayii.

O ni ọna abayọ kan ṣoṣo tijọba apapọ atijọba ipinlẹ le gba yanju iṣoro naa ni ki wọn pese ilẹ ati owo fawọn ileeṣẹ to mọ nipa eto ilegbee yi.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI