Àwọn ọmọ Nàìjíría ní ìpínlẹ̀ Eko ti gba ìgbòrò láti
kọju ìkora ẹya miràn ti àwọn South Africa ń ṣe fún àwọn ọmọ Nàìjíríà.
Ilé ìtàjà ìgbàlóde Shoprite tí agbègbè Lekki ní
ọmọbinrin kan ti gbe ìwé iléwọ láti bu ẹnu àtẹ́ lu ìwá akọlu ti àwọn South
Africa n ṣe si awọn ọmọ Nàìjíríà.
Àwọn míràn tíll ń kigbe pé ki wọ́n dáná sun ilé
itaja náà lójùnà àti ranṣẹ́ pada sí àwọn ènìyàn South Africa gẹ́gẹ́ bi ẹsàn.
Tí ẹ o bá gbàgbé àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè South Africa tí
ń ko sọọbu ti wọ́n sì ń pa àwọn ọmọ Nàìjíríà ni orilẹ̀-èdè wọ́n.
Ìròyìn sọ pé ọ̀pọ̀ àwọn tó ń gba ìgbòro ló ti pàdánù
àwọn ẹbí wọ́n nínú wàhàlá tí àwọn ará South Africa ń dásílẹ̀.
Ẹ fi ọlọ́pàá wa sáàrin ọlọ́pàá yín ní South Africa
fún ààbò àjèjì - ìjọba Nàíjíríà bèèrè
Ijọba ilẹ Naijiria ti kesi ijọba ilẹ South Africa pe
ko yara tete setan lati san owo gba ma binu fun awọn ọmọ Naijiria to fara kaasa
ọpọ ikọlu lati ọwọ awọn ọmọ orilẹede rẹ.
Minisita fọrọ ilẹ okeere lorilẹede Naijiria,
Gofferey Onyeama lo tẹ pẹpẹ ibeere naa siwaju asoju ijọba ilẹ South Africa to
ransẹ pe laarọ oni.
Bakan naa lo koro oju si ijọba ilẹ South Africa pe o
mọọmọ n fi ọrọ titi ọwọ bọ iwe adehun igbọraẹniye laarin orilẹede mejeeji falẹ.
Iwe igbọraẹniye ọhun lo wa lati wa ojutu si bi awọn
ọmọ ilẹ South Africa se maa n kọlu awọn ajeji to wa lorilẹede wọn.
Bakan naa tun ni ijọba Naijiria n beere lọwọ ilẹ
South Africa pe ko fi awọn ọlọpa Naijiria sinu awọn ọlọpa ilẹ South Africa, ki
wọn si tun wa lara awọn asoju ilẹ wa ni South Africa.
"Bí ẹ̀bẹ̀ kò bá dẹ́kun ìkọlù South Africa, ẹ
gbé iléeṣẹ́ aṣojú rẹ̀ ní Nàíjíríà tìpa"
Ẹnu lasan ko le dẹkun ọrọ bi awọn ọmọ bibi orilẹede
South Afrika se n kọlu awọn ajeji, taa mọ si Xenophobia, eyi to ti wa n di
lemọ-lemọ bayii, ayafi ki ijọba Naijiria gbe igbeṣẹ to lagbara lori rẹ.
Eyi ni ero aṣoju ilẹ Naijiria sorileede Uganda tẹlẹ
ri, Ambassador Omolade Oluwateru, ẹni to tun ti jẹ igbakeji gomina tẹlẹ nipinlẹ
Ondo.
Ẹ́ gbọ Oluwatẹru siwaju si:
Ambassador Oluwateru daba yi gẹgẹ bii lọna abayọ
nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, nipa ariwo to gbode lori bi awọn ọmọ orileede
South Africa ṣe n dẹyẹ si awọn ọmọ Naijiria.
Oluwateru ni o ṣeni laanu pe orileede South Afrka ti
Naijiria ti ṣe loore to pọ, ni yoo ma wa fi ẹ̀yin ọbẹ jẹ Naijiria niṣu.
O ni bi ọwọja idẹyẹsi yii ti ṣe wa peleke bayi,
ijọba Naijiria gbọdọ gbe igbese to le, ki South Afrika ba le mọ pe ko fi ọwọ
yẹpẹrẹ mu ẹmi awọn ọmọ ilẹ rẹ lẹyin odi.
''Lẹyin ti Naijiria ba parọwa si South Afrika ti
wọ́n ko gbọ, ohun to yẹ ni ki wọn paṣẹ ki aṣoju Naijiria ni South Afrika pada
wa sile ni kiakia''
O tun ṣalaye pe ti igbeṣẹ yii ba kọ ti ko dẹkun ọrọ
naa, ki Naijiria ti ileeṣẹ asoju South Afrika to wa ni Naijiria pa, ki wọn si
da aṣoju wọn pada si ilẹ wọn.
Nigba ti a beere boya Naijiria le gbe awọn ọmọ ilẹ
rẹ to wa ni South Afrika pada wa sile, Otunba Oluwateru ni o ṣeeṣe ṣugbọn kii
ṣe gbogbo eeyan naa ni yoo fẹ pada wa sile.
''Awọn miran le e ni iṣẹ ti wọn n ṣe nibẹ ati pe, ti
a ba gbe wọn pada, ki ni wọn fẹ́ maa wa ṣe nile? Ẹkọ gbigbona lọrọ yi, o gba ki
a fi suuru to''
Kini Ijọba Naijiria ti ṣe?
Lọwọlọwọ bayii, ijọ̀ba orilẹede Naijiria ti ransẹ ke
si asoju ijọba ilẹ SZouth Africa to wa ni naijiria si ibi ipade kan.
Bakan naa, Minisita fọrọ ilẹ Okeere, Geoffrey
Onyeama loju opo Twitter rẹ, ti wa bẹnu atẹ lu iṣẹlẹ yii, to si ni Naijiria yoo
gbe igbesẹ to peye lori ọrọ naa.
O ni o to gẹ bi wọn ti ṣe n dana sun awọ́n ile itaja
ọmọ Naijiria lorileede South Afrika.
Sugbọn ọpọ Naijiria lo n woye pe ijọba orilẹede yii
ko tii se ohun to yẹ, to ba si fẹ dẹkun ikọlu yii, o gbọdọ san sokoto rẹ ko le
ni.
"A kò ní ra ọjà South Africa mọ́, a ó gbẹ̀san
oró tí wọn ń dá wa - Ọmọ Nàíjíríà fárígá"
Igi gogoro ma gun mi loju, ati okeere la tii wo o, o
wa to asiko bayi ki ijọba Naijiria wa wọrọkọ fi ṣada lori ọrọ ikọlu South
Afrika sawọn ọmọ Naijiria to n di lemọlemọ bayii.
Eyi ni ero ọkan ọpọ ọmọ Naijiria loju opo Twitter
lori iwa idojule ti awọn ọmọ South Afrika n hu si awọn ọmọ Naijiria nilẹ wọn.
Kaakiri oju iwe iroyin ati loju ayelujara ni iroyin
ati fọnran fidio orisirisi ti n ṣe afihan bi wọn ti ṣe n doju ija kọ awọn ọmọ
Naijiria ati ọmọ ilẹ Afrika miran.
Idunkoko awọn ọmọ South Afrika mọ awọn ọmọ orileede
Afrika miran lẹnu ọjọ mẹta yii jẹ ohun to n fọwọ kan ọpọ eeyan lẹmi.
Lara awọn to ti ke gbajare yii la ti ri gbajugbaja
sọrọ sọrọ nii, Daddy Freeze, ti o ni oun ko ni ra ọja kankan to ba jẹ ti
orileede South Afrika mọ.
Arabinrin Faithe marere da lohun pada ti o si darukọ
awọn ile itaja ti o jẹ ti South Afrika, to yẹ ki awọn ọmọ Naijiria dẹyẹ si.
Idẹyẹsi awọn ọmọ ilẹ Afrika lati ọwọ awọn ọmọ South
Afrika ko ṣẹṣẹ ma waye.
Lọpọ igba ni awọn ọmọ Naijiria ti ma n farakasa
iṣẹlẹ yii ,ti o si ti ma n mu ki awọn eeyan kesi ijọba awọn orilẹede mejeeji
lati mu opin ba iru iwa yii.
Pupọ awọn ileeṣẹ South Afrika lo ti pẹka de Naijiria
ti wọn si n ri ere tabua lọdọ awọn eeyan Naijiria.
Eyi wa lara ohun ti o mu ki awọn eeyan Naijiria ma
faraya, bi awọn ọmọ South Afrika ko ti ṣe ni ẹmi amumọra fun awọn eeyan miran.
- BBC
No comments:
Post a Comment