Awọn ọmọ Naijiria ti ko din ni irinwo la gbọ pe wọn ti forukọ silẹ lati fi orilẹ-ede South Afrika silẹ latari bawọn ọmọ orilẹ-ede naa ṣe doju ija kọ wọn, ti wọn si n pa wọn nipakupa bi adiẹ irana.
Ajọ kan ti wọn pe ni Nigerian Mission lorilẹ-ede South Afrika ni wọn fidi ọrọ naa mulẹ laipẹ yi pe awọn ti ṣetan lati ko awọn eeyan naa pada si orilẹ-ede wọn, lati le gba wọn lọwọ iku ojiji to n doju kọ wọn.
A gbọ pe ọkọ baalu ọfẹ ile iṣẹ Air Peace lo gbe eto naa kalẹ lati ko awọn eeyan naa kuro.
No comments:
Post a Comment