WỌN JU AYỌMIDE SẸWỌN L'ABUJA NITORI ẸSUN JIBITI - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, September 5, 2019

WỌN JU AYỌMIDE SẸWỌN L'ABUJA NITORI ẸSUN JIBITI

Oṣu mẹta gbako ni ọdọmọkunrin ẹni ọdun mejilelogun kan, Ojo Ayọmide yoo lo lẹwọn, latari ẹsun jibiti ti ajọ to n gbogun ti iwa ajẹbanu lorilẹ-ede Naijiria, iyẹn Economic and Financial Crime Commission, EFCC fi kan an.

Ọjọru tii ṣe Wẹside la gbọ pe ile ẹjọ giga to fikalẹ siluu Abuja, eyi ti Onidajọ N.E. Maha jẹ oludari ẹ gbe idajọ naa kalẹ, to si ni ẹsun ti wọn fi kan Ayọmide fidi mulẹ, ati pe ojulowo ni.

AWIKONKO gbọ pe orukọ Onimọ-ẹrọ kan ni United States, ẹni to fi Miami, Florida ṣebugbe ni Ayọmide fi n lu awọn eeyan ni jibiti lori ayelujara, fun idi eyi, o ni lati jiya ẹṣẹ rẹ labẹ ofin.

Yatọ si eyi, ile ẹjọ naa tun wa a foju aanu wo Ayọmide, to si fi anfaani silẹ fun un lati san owo itanran, ẹgbẹrun lọna igba, dipo ko lọ ṣẹwọn oṣu mẹta gbako naa, ati pe yoo tọwọ bọwe adehun pe oun ko tun jẹ pada sidi iwa buruku naa mọ.

A ti ẹ gbọ pe ẹka ikẹkọọ iṣiro, iyẹn Accounting ni Ayọmide wa ni fasiti ipinlẹ Ekiti, eyi to wa niluu Ado-Ekiti.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI