WỌN FẸẸ BA TEMI JẸ NI O, EMI KO NI TBOSS BIMỌ FUN O - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, September 8, 2019

WỌN FẸẸ BA TEMI JẸ NI O, EMI KO NI TBOSS BIMỌ FUN O

Ṣẹneto Dino Melaye ti ke gbajare sita pe awọn to n gbe iroyin kaakiri ori ayelujara pe oun ni TBOSS to ti figba kan ri jẹ ọkan lara awọn akopa nibi idije Big Brother Naija bimọ tuntun fun kan fẹẹ ba oun lorukọ jẹ lasan ni.

 
Oni tii ṣe Aiku Sande ni Melaye gba ori ikanni ayelujara ti Twitter ẹ lọ lati jẹ ki gbogbo agbaye mọ pe oun ko mọ nnkankan nipa oyun ti TBOSS naa ni, depodepo wi pe yoo bimọ foun.
Melaye ni, "Mo kan ni lati gboju fo awọn irọ ati ahesọ to n lọ kaakiri wi pe emi ni Baba ọmọ ti Tboss bi. Gbogbo ọmọ lo jẹ ibunkun lati ọrun wa fun gbogbo abiyamọ, ti mo si ki Tboss ku oriire ayọ abara tintin. Fun ẹni to jẹ baba ọmọ, kii ṣe emi rara. Mi o figba kan ri fẹ TBOSS. Ẹyin olodo ni lati mọ eyi daju."

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI