Gbogbo awọn ọmọ
ati olugbe ipinlẹ Ogun patapata ni wọn ti n gbaradi bayii fun ọjọ Abamẹta
Satide ọla, nigba ti ẹlẹkun yoo sunkun, ti alayọ yoo si yọ.
Abajade esi
idajọ ile ẹjọ Tribuna to fẹẹ waye lawọn eeyan n duro de bayii. Nigba tawọn ọmọ
lẹyin Gomina Dapọ Abiọdun tipinlẹ Ogun n sọ pe ko si nnkan o fẹẹ ṣẹlẹ, tori pe ẹjọ
ti Ọnọrebu Adekunle Akinlade, Triple A pe ko lẹsẹ nilẹ rara.
Bẹẹ lawọn ọmọlẹyin
Ọnọrebu Akinlade naa n gbaradi bayii, ko da a, ti a gbọ pe gbogbo eto ti to
patapata lati dana ariya, bi ile ẹjọ ba le kede ọga wọn gẹgẹ bi ẹni to jawe
olubori ninu idibo gomina to waye lọjọ kẹsan an oṣu kẹta ọdun yi.
Fawọn to ba
mọ bi nnkan ṣe n lọ daadaa, wọn a mọ pe lati gba ti ajọ INEC to n dari eto idibo
lorilẹede Naijiria ti kede Ọmọba Dapọ Abiọdun ni Ọnọrebu Akinlade toun gbe
apoti labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APM ti pe ẹjọ ti nọmba ẹ jẹ EPT/OG/GOV/01/19 nile ẹjọ
Tribuna pe oun ko gba esi ibo naa wọle rara, tori pe madaru wa nibẹ.
Gomina Dapọ
Abiọdun gẹgẹ bi a ṣe gbọ ni wọn sọ pe ibo 222,153 lo gbe e wọle, nigba ti Ọnọrebu
Akinlade, Triple A ni ibo 241,670, ti Ọmọba Goyega Nasir isiaka to ṣe ipo kẹta
si ni ibo 110,422 labẹ asia ẹgbẹ oṣelu ADC.
Lọjọ kọkandinlogun
ni Onidajọ Yusuf
Halilu to n dari ẹjọ naa, lẹyin awọn abajade ti igbẹjọ
naa sọ pe kawọn ti wọn n ja si ipo gomina lọ maa gbaradi fun ọjọ kẹrinla oṣu
yi, tii ṣe ọla fun idajọ, nitori pe ọjọ naa i onikaluku wọn yoo mọ ipo to wa.
Nnkan to
daju bayii ni pe, bi idajọ naa ko ba tẹ ẹgbẹ oṣelu APM lọrun, ile ẹjọ kotẹmilọrun
lo n gba lọ, bẹẹ gẹlẹ naa lo ri fun Gomina Dapọ Abiọdun bi ile ẹjọ ba da Ọnọrebu
Akinlade lare.
Bẹ o ba
gbagbe, ko fẹẹ si iyatọ laarin ẹjọ to n lọ lọwọ yi si ẹjo ti Sẹnẹtọ Ademọla
Adeleke to jẹ oludije sipo Gomina nipinlẹ Ọṣun lọdun to kọja pe akẹgbẹ ẹ to
jawe olubori, Alaaji Gboyega gboyega Oyetọla, nibi to ti sọ pe esi ibo naa ko tẹ
oun lọrun.
Ẹ gbọ, bawo
ni yoo ṣe ri lara yin bi ile ẹjọ ba da Gomina Abiọdun lare, ati pe bawo ni yoo ṣe
ri lara yin bi ile ẹjọ ba da Ọnọrebu Akinlade lare?
Ẹ jẹ ka gbọ
ero ọkan yin.
No comments:
Post a Comment