ỌWỌ EFCC TẸ OṢIṢẸ IJỌBA TO N LU JIBITI, MILIỌNU MẸWAA NAIRA OWO OṢU MẸTA AWỌN OṢIṢẸ ABẸ Ẹ LO GBE SALỌ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, September 15, 2019

demo-image

ỌWỌ EFCC TẸ OṢIṢẸ IJỌBA TO N LU JIBITI, MILIỌNU MẸWAA NAIRA OWO OṢU MẸTA AWỌN OṢIṢẸ ABẸ Ẹ LO GBE SALỌ

IMG_ORG_1568529949896
Lọjọ Satide ana ni ajọ to n gbogunti ṣiṣe owo ilu kumọkumọ, iyẹn EFCC tẹ awọn oṣiṣẹ ijọba meji kan, ti wọn tun jẹ ọga patapata lẹnu iṣẹ, iyẹn l'ẹka ti wọn pe ni Marshal nipinlẹ Ṣokoto. 
Abdullahi Sa’idu to jẹ ọga agba ati alakoso patapata (Director General) ati Bashar Dodo-Iya toun jẹ akọwe owo ni Sokoto Marshal Agency lawọn eeyan naa ti wọn sọ pe wọn ko owo ti ko din ni miliọnu mẹwaa naira to jẹ owo oṣu awọn oṣiṣẹ wọn jẹ.

Agbarijọ awọn oṣiṣẹ ti ko din ni mọkandinlogoji ajọ naa la gbọ pe wọn ṣepade, ti wọn si kọwe ẹsun lori wọn lati ṣalaye fun wọn lori bi wọn ṣe ṣe owo oṣu mẹta wọn, eyi ti wọn ko ri gba.

Iwe ẹsun naa la gbọ pe wọn fi ranṣẹ si ajọ EFCC, tawọn yẹn si bẹrẹ igbesẹ, ko too di pe wọn lọọ gbe wọn lọjọ Ẹti Fraide ijẹta. A gbọ pe wọn ko le jẹri gbe ara wọn lori bi wọn ṣe ṣe owo naa, lo mu kaṣiri wọn tu sita.

Ni bayii, ajọ EFCC ti wa a fidi ẹ mulẹ pe awọn yoo foju awọn mejeeji bale ẹjọ laipẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI

Contact Form

Name

Email *

Message *