Ọga agba patapata fun ẹṣọ oju popona nipinlẹ Ogun, Kọmanda Ṣeni
Ogunyẹmi ti sọ pe oluranlọwọ ti ko ṣe e fọwọ rọ ti sẹyin ni ẹgbẹ laabo fijilante, iyẹn Vigilante Group of Nigeria, paapaa nipinlẹ jẹ, nitori pe wọn mọ nipa eto aabo daadaa.
Ọjọbọ Tọside ana ni Kọmanda Ogunyẹmi sọrọ naa nibi abewo ti ẹgbẹ Fijilante ṣe lọ si ileeṣẹ TRACE fun ajọṣepọ to mọnyan lori. Nibẹ lo ti gbe oriyin fun iṣẹ takuntakun ti ẹgbẹ naa n ṣe, bẹẹ lo tun sọ pe ọkan pataki teeyan ko gbọdọ fi ṣere ni Kọmanda nureni Ọlanrewaju Adedoyin to jẹ ọga wọn jẹ.
Nibẹ lo tun ti gbe aami ẹyẹ 'O kare' le ọga agba VGN naa lọwọ, fun iṣẹ ribiribi to n ṣe lati mu ki eto aabo tubọ fẹsẹ rinlẹ kaakiri ipinlẹ Ogun ati agbegbe ẹ.
"Bi a ṣe da ẹgbẹ TRACE silẹ nipinlẹ Ogun naa ni wọn da Fijilante silẹ, a ni lati maa fọwọsowọpọ lati gbe eto aabo larugẹ ni. Bi a ṣe n daabo bo araalu naa la n daabo bo oju popona wa, tori pe nnkan to ṣe pataki niyẹn. Bi a ṣe wulo fun ẹgbẹ Fijilante naa lawọn naa le wulo fun wa. A nilo iranlọwọ ara wa, ka si maa pe ara wa loore-koore.
"Gudugudu meje ati yaya mẹfa lawọn Fijilante n ṣe, paapaa nipinlẹ Ogun ti a wa yii, nitori pe a ti ri awọn ibi tawọn ol ti n ṣọṣẹ, ti wọn n dawọn eeyan laamu lojo popona, to si jẹ pe loju ẹsẹ ti a ba ti pe wọn ni wọn maa da wa lohun. Bi a ṣe n pe awọn ọlọpaa la n pe awọn naa, ti a si n ri gbogbo awọn anfaani ti wọn n ṣe fawọn araalu.
"Bẹẹ la tun sọrọ lori awọn awakọ ti wọn n lo, ti wọn fẹ ki wọn gba idanilẹkọọ lọdọ wa, lati ma maa wa iwakuwa loju popona. Fijilante, paapaa VGN wulo gidigidi fawọn araalu, a si fẹ ki ijọba ba wa fi oju aanu wo awọn naa, paapaa nipa ti ọlọpaa agbegbe ti Aarẹ Muhammadu Buhari mẹnuba.
"Bi a ṣe ni Federal Road Safty Corpse to jẹ tijọba apapọ, bẹẹ naa la ni Traffic Compliance and Enforcement Corps (TRACE) nipinlẹ Ogun, ti a ko si di ara wa lọwọ, ko da, ṣe la n ran ara wa lọwọ. Ifọwọsowọpọ lo ṣe pataki nitori pe aabo araalu lo ṣe koko julọ."
Nigba toun naa n sọrọ, Kọmanda Nureni Adedoyin sọ pe bi aabo ẹmi ati dukia awọn araalu ṣe jẹ pataki si ẹgbẹ wọn, naa tun ni aabo oju popona tun jẹ pataki, idi ni yii tawọn fi gbọdọ maa ni ajọṣepọ loore-koore.
O wa gbe oṣuba kare fun ajọ TRACE wi pe latigba ti wọn ti da wọn silẹ labẹ ofin ni alaafia ti de ba oju popona kaakiri ipinlẹ Ogun, ti wọn si n dahun sawọn ijamba oju popona loju ẹsẹ.
Eto fawọn Araalu ninu oṣu ‘Ba-baa-ba’
Bakan naa nigba to n dahun si awọn eto ti wọn ni fawọn araalu, ọga agba TRACe, Ogunyẹmi sọ pe:
"A ti n sọ ọ tipẹ-tipẹ wi pe oṣu ba-baa-ba kii ṣe oṣu buruku, kii si i ṣe oṣu to n paayan, nitori pe a n fi eto si inawo wa, ati pe asiko naa lawọn eeyan n ṣe oriṣiriṣi nnkan ju. Asiko naa ni eto ọrọ aje maa n gbooro ju, eyi lo fa ti a fi n kanju ju, iwakuwa awọn awakọ wa ma n pọ ju lati tete ri owo pa.
"Idanilẹkọọ ti a fẹẹ ṣe lasiko yi, a fẹe mu lati kekere, awọn ile ẹkọ lasi ti fẹẹ bẹrẹ. Bawọn akẹkọọ ba ti wọle bayii, to ba di oṣu kọkanla ti gbogbo wọn ti farabalẹ sẹnu iṣẹ ati ẹkọ wọn la ma bẹrẹ sii lọ ba wọn kaakiri.
"A fẹẹ sọ nipa ewu to wa ninu ki ọlọkada maa gbe ero mẹrin-marun sori ọkada, ti a si maa sọ ti mọtọ naa fun wọn. Bi wọn ṣe maa n polowo siga pe ẹni to ba n muu ko nii pẹ ko too ku, bẹẹ la fẹẹ sọ fun wọn pe ẹmi ko laarọ bi wọn ba n sa ere asapajude.
"Bakan naa la tun n lọ sawọn garaaji lati bawọn awakọ sọrọ, kii ṣe awọn ẹgbẹ awakọ la fẹẹ ba sọrọ lasiko yi, bi ko ṣe awọn awakọ funra wọn. Kii ṣe akọkọ re e ti a n ṣe iru nnkan bayii, loore-koore ni, nitori pe a ni lati maa ran ara wa leti ni gbogbo igba. Bẹẹ la tun fẹẹ bawọn ero to n wọ mọto naa sọrọ pẹ wọn gbọdọ maa wo mọto ti wọn fẹẹ wọ daadaa, ki wọn too ko sinu ẹ."
No comments:
Post a Comment