O ṢE PATAKI LATI MAA YẸ ILERA ARA WA WO LOORE-KOORE - IJỌBA IPINLẸ OGUN KE GBAJARE - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, September 8, 2019

O ṢE PATAKI LATI MAA YẸ ILERA ARA WA WO LOORE-KOORE - IJỌBA IPINLẸ OGUN KE GBAJARE

Ijọba ipinlẹ Ogun ti ke gbajare sita fawọn araalu pe nnka to le mu ki wọn wa ni Ilera pipe, awọn eeyan gbọdọ maa ye ilera ara wọn wo loore-koore, nitori pe ilera pipe loogun ọrọ.

Igbakeji Gomina, Onimọ-ẹrọ Nọimọt Salakọ-Oyedele lo sọrọ naa lopin ọsẹ to kọja yi nibi ipolongo eto ilera ọfẹ ti wọn ṣe lọ siluu Ilaro, nibi ti ọpọ awọn eeyan ti jẹ anfaani eto ilera ọfẹ naa.

Gbagede yewa Empire to wa nitosi Aafin Ọba Kẹhinde Olugbenle, to jẹ olu tiluu Ilaro ni eto naa ti waye, nibẹ lo si ti ṣalaye fawọn eeyan wipe ipele mẹta ni eto naa pin si, ti wọn si ti ṣe lawọn ilu bii Ọdẹda ati Iliṣan-Rẹmọ.

Nigba to n sọrọ, o ni igbayegbadun awọn ọmọ ati olugbe ipinlẹ naa lo jẹ ijọba logun, ti yoo si maa wa bi wọn yoo ṣe wa layọ ati alaafia ni gbogbo igba, idi ni yii to nijọba ko ni rẹyin lati maa polongo fawọn araalu lati mọ awọn ọna ti wọn yoo maa gba lati wa ni ilera to peye, paa nipa awọn ounjẹ to n ṣe ara loore, atawọn asiko to yẹ kawọn eeyan maa fun ara ni isinmi.

Onimọ-ẹrọ Salakọ-Oyedele ni aarun kan wa nita lasiko yi ti wọn n pe ni hepatitis to gbajumọ daadaa, tawọn si ti sẹtan lati maa polongo bi wọn ṣe le dẹkun aarun naa

Ninu ọrọ Ọba Kẹhinde Olugbenle ti Oloye Emmanuel Adeboye Ṣanu lo ti gbe oṣuba kare fun ijọba ipinlẹ Ogun latari akitiyan lati mu ipinlẹ naa gun oke agba.


Lara awọn nnkan ti wọn ṣe nibẹ ni awọn ayẹwo bii oju, ti wọn si n fawọn to ni aisan ninu oju wọn ni igo; itọ ṣuga, ẹjẹ riru, ifeto si ọmọ bibi atawọn min in.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI