Ṣẹnkẹn bayii lọwọ ọlọpaa ipinlẹ Akwa Ibom tẹ Baale ile kan, Idorenyin Essien, ẹni ọdun marundinlogoji ti wọn loo dana sun ọmọ rẹ latari ẹsun to fi kan ọmọ naa pe o ji owo oun, ẹẹdẹgbẹta naira gbe.
Bo tilẹ jẹ pe "iṣẹ eṣu ni" lọrọ ẹbẹ to n tẹnu Essien jade, ṣugbọn sibẹ, epe rabandẹ lawọn eeyan n gbe ọkunrin naa ṣe lori iwa ọdaju to hu naa, ti wọn si n bẹ awọn ọlọpaa pe ki wọn rii daju pe wọn ran an lọ sẹwọn gbere.
Agbegbe Afia Nsit to wa nijọba ibilẹ Eket niṣẹlẹ naa ti waye lọjọ Fraide ọsẹ to kọja yi, ṣugbọn to jẹ pe ana Tuside lawọn ọlọpaa fidi iṣẹlẹ naa mulẹ lẹyin tọwọ palaba Essien segi.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa, Odiko
Macdon nigba to n fidi ọrọ naa mulẹ bu ẹnu atẹ lu iwa ti Essien hu naa, to si lawọn ko ni i foju aanu wo rara, ati pe gbogbo ọna ti ile ẹjọ yoo fi gbe idajọ ododo kalẹ lawọn yoo gba nitori pe ẹlẹṣẹ kan ko nii lọ lai jiya.
AWIKONKO gbọ pe ọmọ naa ta a forukọ bo laṣiri lọọ ji owo ẹẹdẹgbẹta naira, to si lọọ fi ra ounjẹ latari ebi to n pa a, tori ti wọn sọ pe iya ni baba rẹ fi n jẹ, kii sii fun lounjẹ lasiko. Bi Essien ṣe gbọ ni wọn loo lọ san owo naa.
Bo si ṣe pada sile lo ran ọmọ rẹ yin ni karosiini, pẹluu idunnu la gbọ pe ọmọ naa fi sare lọọ ra lai mọ pe baba rẹ ni erongba buruku lọkan sii. Bo ṣe pada de, ni wọn ni Essien fi okun de ọmọ naa, to si gbe e siwaju ita, nibi to ti da karosiini naa si i lara, to si ju ina sii.
Awọn ara adugbo to wa nitosi la gbọ pe wọn doola ẹmi ọmọ naa la ti gbe e lọ si ọsibitu, ṣugbọn o ṣeni laanu pe oju ọna lọmọ naa dakẹ sii.
No comments:
Post a Comment