NITORI AWỌN ILEEṢẸ TUNTUN, IJỌBA IPINLẸ OGUN ṢELERI LATI TUN GBOGBO OPOPONA ṢE - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, September 12, 2019

NITORI AWỌN ILEEṢẸ TUNTUN, IJỌBA IPINLẸ OGUN ṢELERI LATI TUN GBOGBO OPOPONA ṢE


Lojuna lati mu igbayegbadun ati ija-geere ọkọ lawọn opopona kaakiri, ijọba ipinlẹ Ogun labẹ Gomina Dapọ Abiọdun ti ṣeleri wi pe gbogbo awọn ọna kaakiri ipinlẹ naa loun yoo ṣe.

Gomina Abiọdun, ti igbakeji rẹ, Onimọ-ẹrọ Nọimọt Salakọ Oyedele ṣoju fun lo fidi ọrọ yi mulẹ laipẹ yi nibi ayẹyẹ ogoji ọjọ ti ileeṣẹ to n ṣe ọkọ, iyẹn Honda ti de si orilẹ-ede Naijiria.
Oni awọn opopona kan wa to jẹ pe ibẹ ni agbara ipinlẹ Ogun, nitori pe ibi ti owo ti n wọle ju sapo ijọba niyẹ, iyẹn awọn agbegbe bii Sango, Ọta si Agbara atawọn min in lo ti pọn dandan fun ijọba lati ṣe atunṣe to ba yẹ lee lori.

Bẹẹ lo tun jẹ ko di mimọ pe ko nii ṣe apati iṣẹ kankan, nitori pe gbogbo awọn ẹka to le mu idagbasoke ba ipinlẹ naa lawọn yoo ṣiṣẹ lori wọn, fawọn ileeṣẹ nla-nla ati kereje-kereje le ri owo to to lati jẹ eere repẹtẹ, ati pe oun atijọba ipinlẹ Ekoo ti ṣetan lati fọwọsowọpọ lati wa ọna abayọ si igbokegbodo ọkọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI