KO SẸNI TO LE DA ARABAMBI DURO GẸGẸ BI ALAGA ẸGBẸ OṢELU LABOUR L’OGUN – ABDULSALAM PARIWO SITA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, September 13, 2019

KO SẸNI TO LE DA ARABAMBI DURO GẸGẸ BI ALAGA ẸGBẸ OṢELU LABOUR L’OGUN – ABDULSALAM PARIWO SITA

Afaimọ ki wahala to n ṣẹlẹ ninu ẹgbẹ oṣelu Labour nipinlẹ Ogun, paapaa lorilẹede Naijiria ma tun pada gba ọna min in yọ, latari bi ẹgbẹ naa ṣe ti pin bayii, ti wọn si n fojoojumọ da Kọmureedi Abayọmi Arabambi duro gẹgẹ bi alaga nipinlẹ Ogun.
 
Lọjọ Tọside ana niroyin kan tẹ AWIKONKO lọwọ pe ẹgbẹ oṣelu Labour lapapọ niluu Abuja ti da alaga ẹgbẹ naa nipinlẹ Ogun, iyẹn Kọmureedi Abayọmi Arabambi duro, eyi ti wọn ni igbakeji alaga lapapọ, iyẹn Kọmureedi Bọde Simeon fọwọ si.

Ninu atẹjade naa to tẹ AWIKONKO lọwọ laarọ oni la gbọ pe Kọmureedi Bọde Thomas ti pe ipade awọn oloye ẹgbẹ naa nipinlẹ Ogun, ti wọn ko si pe Arabambi to jẹ alaga sii, nibẹ la bọ pe wọn ti fẹnu ko lati da ọkunrin naa duro latari awọn ẹsun oriṣiriṣi ti wọn fi kan an.

Nibẹ ni wọn ni Simeon ti sọ pe alaga wọn patapata lo paa laṣẹ foun lati wa a ṣe ipade naa, ki wọn le tete yọ igi wọrọkọ to n da ina ru ninu ẹgbẹ naa, ki atunṣe ati atunto le wa.

Awọn oloye ẹgbẹ naa ninu ọrọ wọn sọ pe agabagebe Arabambi ti pọ ju, ati pe awọn ko nigbagbọ ninu ẹ mọ, idi ni yi ti a gbọ pe wọn fẹnuko pe ko lọọ jokoo sile titi digba ti wọn yoo fi wa ojutuu sọrọ naa.

Loju ẹsẹ ni wọn ti gbe ẹlomin in, iyẹn Kọmureedi Babatunde Ranti Atanda, ẹni to jẹ alaga ẹgbẹ naa laarin gbungbun ipinlẹ Ogun, iyẹn Senatorial Chairman dide lati di ipo naa mu fungba diẹ, tii ṣe alaga fidihẹ.

Bi iroyin naa ṣe jade sita ni Kọmureedi Arabambi ti sọ pe ayederu lawọn pe ipade naa, nitori pe alaga wọn lapapọ, iyẹn Kọmureedi Abdulkadir Abdulsalam ti sọ pe wọn ko gbọdọ ṣe ipade kankan, ayafi toun ba fọwọ sii.

Ṣaaju asiko yi la gbọ pe awọn igun kan ninu ẹgbẹ oṣelu naa nipinlẹ Ogun ti kọ lẹta si ẹgbẹ naa lapapọ wipe awọn fẹẹ yọ alaga wọn, awọn yoo si ṣe e nita gbangba, iyẹn niwaju awọn oniroyin. Bi lẹta naa ṣe tẹ alaga lapapọ lọwọ lo ti paṣẹ fun igbakeji rẹ pe wọn ko gbọdọ tii ṣe ipade kankan, depodepo wi pe wọn yoo yọ Arabambi nipo.


Nigba to n b’AWIKONKO sọrọ laarọ oni, Kọmureedi Abdulkabir Abdulsalam to jẹ alaga ẹgbẹ naa lapapọ sọ pe “Bọde Simeon ko ni aṣẹ kankan lati pe ipade awọn oniroyin, nitori pe mo ti sọ fun un ko too lọ siluu Abẹokuta pe ko gbọdọ lọọ ṣepade kankan. Mi o si fun ẹnikẹni laṣẹ lati pe ipade pe ki wọn yọ Arabambi. 


“Mo tun fi atẹjiṣẹ ranṣẹ sii lori foonu pe ko gbọdọ ṣepade bawọn ṣepade kankan niluu Abẹokuta. Fun idi eyi, ko sẹni to le yọ Arabambi nipo gẹgẹ bi alaga lai ni aṣẹ emi ti mo jẹ olori wọn ninu. Wọn kan fẹẹ ba ẹgbẹ jẹ.”

Bakan naa, nigba to n sọrọ, Kọmureedi Abayọmi Arabambi sọ pe ko si ọrọ kankan lẹnu toun, bi ko ṣe pe nnkan ti ọga awọn patapata ninu ẹgbẹ oṣelu labour ba ti sọ ni abẹ ge.

Ni bayii, a gbọ pe wahala nla lo ti bẹ silẹ laarin igbakeji alaga ẹgbẹ naa lapapọ, Kọmureedi Bọde Simeon ati alaga wọn, Kọmureedi Abdusalam bayii, ta a si gbọ pe afaimọ koun naa ma pada gba iwe lo gbele ẹ fungba diẹ, latari bo ṣe tapa si aṣẹ ọga ẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI