IJỌBA IPINLẸ OGUN PE FUN ETO AABO ẸLẸKUN-O-JẸKUN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, September 4, 2019

IJỌBA IPINLẸ OGUN PE FUN ETO AABO ẸLẸKUN-O-JẸKUN

Ijọba ipinlẹ Ogun labẹ Gomina Dapọ Abiọdun ti pe fun eto aabo ẹlẹkun-o-jẹkun wipe ohun nikan lo le mu ki eto aabo to peregede julọ wa nilẹ Yoruba, ati pe yoo mu ki ajọṣepọ to mọnyanlori wa laarin gbogbo ileeṣẹ eleto aabo patapata.

Igbakeji Gomina ipinlẹ Ogun, Onimọ-ẹrọ Nọimọt Salakọ-Oyedele lo fidi ọrọ yi mulẹ nibi apero ati ipade awọn Gomina ilẹ Yoruba to nii ṣe pẹluu eto aabo, eyi to waye laipẹ yi ninu gbọngan International Conference Centre to wa fasiti Ibadan (nuiversity of Ibadan.

Nibẹ lo ti sọ pe eto aabo ẹmi ati dukia awọn araalu lo jẹ ijọba to n fẹ ilọsiwaju ilu logun, eyi ti wọn si gbọdọ jẹ ki itakun eto aabo fẹsẹ mulẹ daadaa kaakiri. Bakan naa lo mẹnuba awọn iṣoro ati adojukọ to n kọju eto aabo lawọn aala laarin ipinlẹ Ogun sipinlẹ Eko ati ipinlẹ Ogun silẹ Olominira Benin, to si n bẹbẹ fun ajọṣepọ ati ifọwọsowọpọ, nitori pe ipinlẹ naa ko le daa ṣe.

Bakan naa ni Gomina alaga awọn Gomina naa, Ọmọwe Kayọde Fayẹmi ti igbakeji rẹ, Ọtunba Adebisi Ẹgbẹyẹmi ṣoju fun gbe oriyin fun ọga agba ọlọpaa orilẹ-ede yi fun ipa to n ko nipa eto aabo orilẹ-ede yi, paapaa ilẹ Yoruba, to si ti kapa awọn to n gbogun ti eto aabo ilẹ Yoruba.

Bẹẹ loun naa pe fun ifọwọsowọpọ awọn ileeṣẹ eleto aabo yooku lati gbaruku ti wọn, ki idagbasoke le tubọ ba orilẹ-ede Naijiria.

Siwaju sii ni Ọọni Ile Ifẹ, Ọba Ẹnitan Adeyẹye Ogunwusi naa gbawọn ti ọrọ kan lamọnran pe ki wọn jẹ ki eto aabo jẹ wọn logun, nitori pe oun ni atẹgun fun alaafia ati iṣọkan orilẹ-ede, to si ṣe sadankata fun awọn Gomina nipa fifọwọsowọpọ lati gbogun ti iṣoro to n doju kọ eto aabo.

Lara awọn to tun wa nibẹ ni Alake ilẹ Ẹgba atawọn Gomina yooku.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI