Ileeṣẹ to n ri si ṣiṣe owo ilu kumọkumọ ati jibiti, Economic and Financial Crimes Commission, iyẹn EFCC tun ti kede sita pe ko din ni marun lọwọ awọn tun tẹ lori ẹsun wi pe wọn n lu jibiti ori ẹrọ ayelujara, iyẹn intanẹẹti.
Ilu Ilọrin nipinlẹ Kwara lọwọ ti tẹ awọn marun-un naa ti wọn pe orukọ wọn ni Stephen Ọdanye, Abọlarin Kayọde, Babatunde Muhammad, Adepọju Tọmiwa ati
Akinbamidele Fẹmi.
Agbegbe ọtọọtọ la gbọ pe ọwọ ti tẹ awọn marun un naa niluu Ilọrin latari olobo ti ti wọn lawọn kan ta ajọ EFCC naa laipẹ yi.
A gbọ pe ori foonu ati ẹrọ alagbeeka tii ṣe kọmputa lawọn eeyan naa ti n lu awọn oyinbo to ba ko si wọn lọwọ ni jibiti obitibiti owo,to si jẹ pe oriṣiriṣi owo ilẹ okeere bii Pọun, Dọla, Yẹn ati bẹẹbẹẹ lọ ni wọn ba ninu apo ile ifowopamọ si wọn lẹyin taṣiri wọn tu.
Foonu towo ẹ le ni ẹgbẹrun lọna ẹgbẹrun, mọto bọginni-bọginni atawọn ayederu iwe ti wọn fi n lu jibiti ni wọn tun gba lọwọ wọn loju ẹsẹ tọwọ palaba wọn segi.
Ajọ naa ti wa a fi da gbogbo eeyan loju pe ko ni pẹ tawọn yoo fi foju awọn eeyan naa bale ẹjọ lati gba idajọ to tọ si wọn.
No comments:
Post a Comment