Titi dasiko ti a ṣakojọpọ
iroyin yi tan, ko tii sẹni to le sọ pato ibi ti ọrọ aawọ to wa laarin ẹgbẹ
alaabo meji nni nipinlẹ Ogun, iyẹn ẹgbẹ SO SAFE CORP ati ẹgbẹ Vigilante Group
of Nigeria yo pari si, lori bawọn ọga agba naa ṣe n gbena woju ara wọn.
Bo tilẹ jẹ pe aawọ naa ti wa
nilẹ lati bi ọdun marun sẹyin, to si ti lọ silẹ, ṣugbọn ṣe lọrọ naa tun gba ibo
miran yọ lọsẹ to kọja yi nigba ti ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun foju awọn ọdaran
mẹta kan han sita fun gbogbo agbaye pe wọn ṣeku pa akekọọ fasiti Ọlabisi
Ọnabanjọ kan ti wọn pe orukọ ẹ ni Ahmed Obisanwo.
Awọn ọdaran naa ti wọn sọ pe
ọmọ ẹgbẹ fijilante ti wọn pe ni Yaluwọn lawọn mẹtẹẹta tii ṣe Idowu Ayọdele ti
inagijẹ rẹ n jẹ Olori-Ọdọ, Ṣẹgun Obisanwo ti inagijẹ rẹ n jẹ Kikiṣore ati Salisu
Akeem.
Biroyin naa ṣe jade sita la gbọ
pe o ti da wahala nla silẹ laarin ẹgbẹ alaabo So Safe ati VGN, tawọn mejeeji si
n fẹsun kan ara wọn loriṣiriṣi.
AWIKONKO gbọ pe lonii ni ẹgbẹ
to nii ṣe peluu awọn ọlọpaa ati araalu, iyẹn Police Community Relations
Commission (PCRC) gba ọfiisi ọga agba ẹgbẹ alaabo So Safe ti Kọmanda Olusọji
Ganzallo jẹ olori wọn lọ lati lọọ sọ pe digbi lawọn wa lẹyin ẹ, ati pe gbogbo
nnkan ti yoo ba gba lawọn yoo fi gbarukuti ẹgbẹ naa.
Gẹgẹ bi awọn to fi bi ipade naa
ṣe lọ to AWIKONKO leti, a gbọ pe abẹwo iṣọkan ati atilẹyin eyi ti oloyinbo n pe
ni Solidarity Visit lawọn ẹgbẹ PCRC, ẹka ti Abẹokuta Mẹtro ati ẹka Adatan Royal
naa ṣe lọ.
Nibẹ la gbọ pe Alaga ẹgbẹ naa
ti Abẹokuta Metro, Ọnọrebu Yọmi Whyte ti sọ pe eeyan gidi ati adari rere lawọn
mọ Ọgbẹni Sọji Ganzallo si, to si jẹ pe ko sibi tawọn ti pade ẹ ti kii tẹriba
fun tọmọde ati agba, idi ni yii tawọn fi dide atilẹyin fun ẹgbẹkẹgbẹ to ba fẹẹ
koju wọn lọna odi.
O
ni gbogbo eto lo ti pari lati rii pe awọn foju Adedoyin bale ẹjọ bo ba
kọ lati lọọ tuuba nita gbangba, nitori pe awọn ko nii la oju awọn silẹ,
ki wọn maa fi eto aabo ipinlẹ Ogun ṣere, to si jẹ pe alaafia lo yẹ ko
jẹẹ logun
Ọnọrebu Whyte ninu ọrọ ẹ, o sọ pe “Gbogbo ọna la maa gba lati rii pe ọga agba VGN naa, Ọgbẹni Ọlanrewaju Nureni Adedoyin bọ sita gbangba lati ko gbogbo ọrọ to sọ lọsẹ to kọja jẹ, ko si jẹ ki gbogbo agbaye mọ pe ọrọ toun ti kọkọ sọ ṣaaju ko ri bẹẹ.
“Bi ko ba ṣe bẹẹ, ko ti i ṣe daadaa to. O gbọdọ lọ bawọn oniroyin, ko si tun lọ sori redio lati bẹbẹ nita gbangba, nitori pe eti to ba gbọ alọ gbọdọ gbọ abọ. Mo fẹ ki ẹgbẹ So Safe mọ pe awa PCRC ti agbegbe Abẹokuta ati Adatan wa lẹyin yin digbi. A ti n ṣatilẹyin bayii tipẹ, a si maa rii pe a ko ni i dawọ duro lati maa ni ajọṣepọ gidi.”
Bakan naa, olori ọdọ ẹgbẹ PCRC naa sọ pe “Bi ọga agba So Safe ba loun yoo fọwọlẹran lati maa wọ ẹgbẹ alatako yi niran, o ṣee ṣe ki wọn yẹ aga mọ wọn nidi, nitori naa, wọn gbọdọ gbe igbesẹ lati rii pe wọn foju bale ẹjọ bi wọn ko ba lọ bẹbẹ nita gbangba."
Nigba toun naa n sọrọ, Sọji
Ganzallo sọ pe awọn ti kọwe ranṣẹ si ọga agba VGN naa, Ọgbẹni Nureni Adedoyin
lati ko gbogbo awọn ọrọ ibanilorukọjẹ rẹ jẹ, ko si lọ bẹbẹ nita gbangba pe iṣẹ
eṣu ni, bi bẹẹ kọ, bebe ẹwọn lo n rin.
O lawọn ti fun ọkunrin naa ni gbedeke
ọjọ ti yoo fi ṣe bẹẹ, ati pe Kọmiṣana ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Bashir Makama ti gba
oun lamọnran pe kiii ṣe gbogbo ariwo ọja loun gbọdọ maa da si, ṣugtbọn eyi to
ṣẹlẹ yi, ibanilorukọ jẹ teeyan gbọdọ gboju foda ni.
No comments:
Post a Comment