Ẹ WO AWỌN ỌMỌ CRITIANO RONALDO NIGBA TI BABA WỌN GBA SAWỌN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, September 11, 2019

Ẹ WO AWỌN ỌMỌ CRITIANO RONALDO NIGBA TI BABA WỌN GBA SAWỌN

Pupọ awọn to ri fidio ti iyawo gbajugbaja agbabọọlu, ọmọ bibi orilẹ-ede Portugal nni, Cristiano Ronaldo, Georgina Rodriguez ya nigba tawọn ọmọ wọn mẹtẹẹta n yọ ayọ lasiko ti baba wọn Ronaldo gba bọọlu ni wọn n rẹrin, ti inu wọn si n dun sawọn ọmọ wọn yii.

 
Ohun o n ya ọpọ awọn to ri fidio naa lẹnu ni pe bawo lawọn ọmọ naa ṣe ti mọ biwọn ṣe n wo bọọlu, pẹluu bi ọjọ ori wọn ṣe kere to, paapaa nigba ti wọn tun ṣafihan baba wọn lori amohunmaworan, uyẹn tẹlifiṣan.

 
Wọn ni bawọn ọmọ naa ṣe maa n yọ ayọ re e, lasiko ti baba wọn ba n gba bọọlu lọwọ, ti wọn yo maa fo soke ati silẹ.

 
Bi wọn ba fi aworan ran baba wọn han, ṣe lawọn ọmọ naa yoo sare lọ sibẹ, ti wọn yoo si maa pariwo 'Papa'.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI