Ẹ GBỌ NNKAN TI ỌṢINBAJO SỌ NIPA AYEDERU IROYIN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, September 13, 2019

Ẹ GBỌ NNKAN TI ỌṢINBAJO SỌ NIPA AYEDERU IROYIN

Alẹ ana tii ṣe Ọjọbọ Tọside igbakeji Aarẹ orilẹ-ede yi, Ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajo
kanminu lori ayederu iroyin to lawọn eeyan maa n gbe kaakiri ori ẹrọ ati ikanni ayelujara, to si ni nnkan ti ko bojumu rara ni.

Ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajo sọrọ yi nibi akanṣe apejọ ounjẹ alẹ to bawọn Ọjọgbọn lẹka iṣẹ iroyin ṣe niluu Abuja, nibẹ lo ti jẹ ko di mimọ pe awọn ayederu iroyin tawọn kan maa n gbe kaakiri ikanni ayelujara maa n ṣakoba fun idasoke ati ilọsiwaju orilẹ-ede, fun idi eyi, o gbawọn lamọnran pe ki wọn wa nnka ṣe si.

O jẹ ko di mimọ pe  "Idasilẹ ikanni ayelujara ti jẹ ki ayederu iroyin tubọ gbilẹ sii, ati pe ẹdun ọkan ni ayederu iroyin tabi awọn ọrọ agbẹlẹkọ ma n jẹ, to si maa n da wahala, ainifọkanbalẹ, paapaa ogun ati iku ojiji silẹ.

"Mo ro pe gbogbo awa ti a wa nidi iroyin, yala ori ayelujara, iwe iroyin, amohunmaworan la gbọdọ wa nnkan ṣe sọrọ ayederu iroyin, ko too bẹrẹ sii gbe wa ṣubu."

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI