DAPỌ ABIỌDUN YẸ ỌNỌREBU AKINLADE GBALẸ NILE ẸJỌ TRIBUNA, NI ADAJỌ BA LAWỌN KAN FẸẸ TAN OUN LỌ SORI OKE OLUMỌ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, September 14, 2019

DAPỌ ABIỌDUN YẸ ỌNỌREBU AKINLADE GBALẸ NILE ẸJỌ TRIBUNA, NI ADAJỌ BA LAWỌN KAN FẸẸ TAN OUN LỌ SORI OKE OLUMỌ

Ṣe ni idunnu ṣubu lu ayọ awọnlẹyin Gomina ipinlẹ Ogun, Ọmọba Dapọ Abiọdun lonii, nigba ti Onidajọ Yusuf Halilu kede pe oun da ẹjọ ti Oludije sipo Gomina labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APM, Ọnọrebu Adekunle Akinlade nu, nitori pe ko lẹsẹ nilẹ rara, ati pe ibo ti Gomina Dapọ Abiọdun fi bori ṣoju ṣaara.

Ni kete ti Onidajọ Halilu sọrọ naa lawọn ololufẹ Gomina Abiọdun ti gbe ilu, ti wọn si bẹrẹ sii lu kaakiri ipinlẹ naa fun aṣeyọri naa, paapaa layika ile ẹjọ Maijisireeti to wa niluu Abẹokuta, nibi ti idajọ naa ti waye.

Onidajọ Halilu sọ pe ibo 241,670 ni Gomina Abiọdun fi bori Ọnọrebu Akinlade toun ni ibo 222,153 ninu idibo to waye loṣu kẹta ọdun yi.

Aago mẹwaa kọja iṣẹju meje gbako ni eto idajọ naa bẹrẹ, to si pari laago mẹrin ku iṣẹju mẹfa lonii Satide Abamẹta.

Nigba to n kadi ọrọ rẹ nilẹ, Onidajọ Halilu sọ pe nigba toun de siluu Abẹokuta lati bẹrẹ ẹjọ naa, awọn kan ninu awọn tawọn jọ n ṣiṣẹ sọ pe koun wa a lọ si Oke kan to gbajumọ daadaa, to si jẹ orirun ilu Abẹokuta lati daraya.

O ni oun sọ pe kii ṣe nnkan toun wa a ṣe niyẹn, nitori pe boun ba lọọ fi ẹsẹ kọ, toun ṣubu, toun si farapa, ohun tawọn eeyan yoo maa sọ ni pe oun ko gbajumọ iṣẹ ti wọn gbe le oun lọwọ, fun idi eyi, o loun sọ fun wọn pe asiko ko tii to lati lọọ gbafẹ, nitori pe iṣẹ loun wa a ṣe, kii ṣe igbafẹ.

Ohun kan ti Onidajọ naa tun sọ ni pe oun da ẹjọ naa nibamu pẹlu ofin ati ẹri ọkan oun, kii ṣe pe boya oun gba owo, ati pe boun ko ba da ẹjọ naa bo ṣe yẹ, asiko kan n bọ toun yoo sun, toun ko si ni ji pada saye, yoo wa ku oun ati Ọlọrun to da oun, lati ṣedajọ to ba yẹ foun.

Nitori naa, o loun da ẹjọ naa lai ṣe ojuṣaaju ẹnikẹni.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI