AGUNBANIRỌ, ỌMỌDUN MẸRINDINLỌGBỌN DI KỌMIṢANA NI KWARA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, September 18, 2019

AGUNBANIRỌ, ỌMỌDUN MẸRINDINLỌGBỌN DI KỌMIṢANA NI KWARA

Ijọba ipinlẹ Kwara labẹ iṣakoso Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti fi orukọ awọn obinrin mẹrin kan ṣọwọ sile igbimọ aṣofin ipinlẹ naa lati ṣe agbeyẹwo wọn gẹgẹ bii Kọmisana, eyi ti ọkan lara wọn jẹ ọmọdun mẹrindinlọgbọn.

Joana Nnazua Kolo lati ijọba ibilẹ Edu ni ọmọdun mẹrindinlọgbọn naa la gbọ pe Gomina ni ipinu lati jẹ ko wa ninu awọn obinrin mẹrin ti yoo ba a dari iṣakoso ẹ. Ọdun to kọja lo kẹkọọ gboye nile ẹkọ fasiti ipinlẹ Kwara lẹka ikẹkọọ yara ikawe, iyẹn Library Science.

Yatọ si Joana, lara awọn ti Gomina AbdulRazaq tun fi orukọ wọn ranṣẹ ni Arabinrin Fọlṣade Ọmọniyi to jẹ alakoso ati oludari ile ifowopamọ First Bank Mortgages Limited lati dari ẹka ipawo-wọle, iyẹn (Kwara State Internal Revenue Service).

Awọn yooku ni Ọmọwe ati ọjọgbọn nidi oṣelu; Arabinrin Sa’adatu Modibbo-Kawu; Arinọla Fatimọh Lawal; ati Aisha Ahman Pategi, ta a si gbọ pe ọjọ Tuside ana ni abẹnugọn ile igbimọ aṣofin ipinlẹ naa, Ọnọrebu Salihu Yakubu Danladi ka a si gbogbo awọn eeyan leti.

Ohun to n ya awọn lẹnu ni pe Kolo ṣi n sin orilẹ-ede baba rẹ, iyẹn agunbanirọ lọwọ nile ẹkọ girama ti Model Boarding to wa ni Guri nipinlẹ Jigawa. Ohun si ni yoo jẹ Kọmiṣana to kere ju ninu itan, ti yoo si gba ife lọwọ Oluwaṣeun Fakorede tipinlẹ Ọyọ toun jẹ ọmọdun mẹtadinlọgbọn.

AWIKONKO gbọ pe ọsẹ meji si asiko yi ni yoo pari agunbanirọ rẹ, ko too di pe wọn bẹrẹ igbesẹ lati fọrọ wa a lẹnu wo fun ipo naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI