TANI ALAGA AJỌ CORPORATE AFFAIRS COMMISSION LORILẸEDE NAIJIRIA BAYII??? - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, August 8, 2019

TANI ALAGA AJỌ CORPORATE AFFAIRS COMMISSION LORILẸEDE NAIJIRIA BAYII???

Ibeere tawọn kan n beere lasiko yi ni pe “Tani Alaga Ajọ Iforukọsilẹ Okoowo ati Ileeṣẹ, iyẹn Corporate Affairs Commision” lorilẹede Naijiria lọwọlọwọ bayii, ti ko si tii sẹni to le fidi ẹ mulẹ pe ẹni bayi ni.

Ohun tawọn kan n sọ ni pe Gomina ipinlẹ Ogun, Ọmọba Dapọ Abiọdun ṣi ni alaga ajọ iforukọsilẹ titi dasiko yi, ṣugbọn ti a ko tii le fidi rẹ mulẹ, latari pe Aarẹ Muhammadu Buhari ko tii kede ẹlomin in, tabi yan alaga fidihẹ min in.

Fawọn to ba mọ, tabi awọn ti ko ba mọ, ọjọ kinni, oṣu kẹta ọdun to kọja, iyẹn 2018 ni Aarẹ Muhammadu Buhari ṣe ibura fun Gomina Dapọ Abiọdun gẹgẹ bi alaga ajọ naa niluu Abuja.

Ni nnkan bi oṣu kẹsan an ọdun to kọja ni Ọmọba Dapọ Abiọdun darapọ mọ idije ipo Gomina ipinlẹ Ogun, eyi to pada gbe e wọle loṣu kẹta ọdun.

Ṣugbọn ohun to n ṣe ọpọ awọn eeyan ni kayeefi titi di asiko ti a ṣakojọpọ iroyin yi tan, ni pe ko tii sẹni to le fidi rẹ mulẹ pe Ọmọba Dapọ Abiọdun ti kọwe fipo silẹ gẹgẹ bi alaga ajọ naa.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, apa kan ninu iwe ofin ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress to gbe Gomina Abiọdun fi ye wa pe “Ẹnikẹni to ba ni ifẹ lati du ipo oṣelu lorilẹede Naijiria labẹ asia ẹgbẹ naa gbọdọ kọwe fipo ijọba tabi iṣẹ yoowu to le maa ṣe silẹ, to si gbọdọ fi iwe aridaju han lẹyin ọgbọn ọjọ to ba kede ifiposilẹ.” (Article 30, subsection III).

Iyalẹnu lo jẹ nigba ti wọn sọ pe Ọmọba Dapọ Abiọdun ko tii kọwe fipo silẹ ko too gbe apoti, ati paapaa lẹyin ti wọn dibo yan an gẹgẹ bii Gomina ipinlẹ Ogun.

Ohun to jẹ ki ọrọ naa jade sita ni pe ko tii si iroyin kankan to le fidi rẹ mulẹ titi dasiko yi pe ẹlomin in ti gba ipo alaga ajọ iforukọsilẹ (CAC), eyi gan an lo jẹ aridaju pe ipo nla meji ọtọọtọ ni Gomina Abiọdun n di mu lorilẹede Naijiria, to si jẹ pe bo ṣe gba owo oṣu gẹgẹ bi alaga ajọ CAC naa lo n gba owo oṣu gẹgẹ bi Gomina.

Iwadii ti a ṣe lọ si ori ayẹlujara ajọ iforukọsilẹ http://new.cac.gov.ng/home/chairman-acting-registrar-generalceo-cac-visited-rwanda-high-commission-office-abuja/ fi ye wa pe Gomina Abiọdun ṣi ni alaga.

Gbogbo akitiyan lati ba akọwe iroyin Gomina, Ọgbẹni Kunle Ṣomọrin sọrọ lati gbọ tẹnu ẹ lo ja si pabo dasiko ti a ṣakojọpọ iroyin yi tan.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI