Ṣẹnkẹn bayii ninu gbogbo awọn oṣiṣẹ-fẹyinti patapata, atawọn oṣiṣẹ ti wọn ti n sunmọ ifẹyinti wọn nipinlẹ Ọyọ n dun lasiko yi, pẹluu bi ijọba ṣe kede sita pe oun ti ṣetan lati fi redio ti yoo maa jẹ ki wọn fi erongba wọn han sita, iyẹn Pensioners Radio lọlẹ loṣu kẹsan an ọdun yi.
Akọwe ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ-fẹyinti nipinlẹ Ọyọ, Kọmureedi Ṣẹgun Abatan lo fidi ọrọ naa mulẹ fawọn eeyan laipẹ yi nigba ti awọn igbimọ iṣakoso ileeṣẹ ijọba to n ri sọrọ Iroyin, Aṣa ati Irin Ajo Afẹ, eyi ti Dọkitọ Bashir Ọlanrewaju to jẹ akọwe agba lewaju wọn lọọ ṣabẹwo si ọfiisi wọn to lagbegbe Jẹricho, niluu Ibadan.
Kọmureedi Abatan sọ ninu ọrọ rẹ pe akọkọ iru ẹ nilẹ Adulawọ ni redio naa, to si jẹ pe lati maa fi da si igbe aye awọn oṣiṣẹ-fẹyinti patapata, atawọn ọrọ to ba n lọ lawujọ ni erongba lati da redio naa silẹ.
Ninu ọrọ rẹ, Akọwe agba naa, Dọkitọ Bashir Ọlanrewaju sọ pe ipenija nla ni redio naa jẹ fun gbogbo awọn ẹgbẹ yooku nipinlẹ Ọyọ ati lorilẹede Naijiria, tawọn naa si gbọdọ wa nnkan to le mu wọn dagba soke siwaju sii.
Bẹẹ la tun gbọ pe gbọngan ti wọn tun kọ sinu ileeṣẹ redio tuntun yoo gba to eeyan ẹgbẹrun kan fun oniruuru ayẹyẹ, bẹẹ naa la tun gbọ pe wọn kọ agbegbe imọ igbalode, iyẹn ICT centre sinu ọgba naa.
No comments:
Post a Comment