ỌWỌ TẸ IDAHOSA, OGBOLOGBO ỌMỌ YAHOO L'AJAH, ORIṢIRIṢI OOGUN ABẸNUGỌNGỌ NI WỌN KA MỌN ỌN LỌWỌ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, August 6, 2019

ỌWỌ TẸ IDAHOSA, OGBOLOGBO ỌMỌ YAHOO L'AJAH, ORIṢIRIṢI OOGUN ABẸNUGỌNGỌ NI WỌN KA MỌN ỌN LỌWỌ

Bi ẹ ṣe n ka iroyin yi, gbajumọ ọmọ Yahoo kan ti wọn pe orukọ ẹ ni Victor Idahosa ti wa lahamọ awọn ajọ to n gbogun ti ṣiṣe owo kumọkumọ, iyẹn, EFCC latari bọwọ ṣe tẹ ẹ laipẹ yii.

Agbegbe Lekki ni Ajah, nipinlẹ Eko la gbọ pe ọwọ palaba Victor, ọmọdun mẹrinlelogun ti segi, iyẹn ladugbo Cristolyte, Daimond Estate nigba ti wọn lawọn oṣiṣẹ EFCC fura sii, ti ọn si da a duro.

 
Bi wọn ṣe da a duro la gbọ pe wọn bẹrẹ sii beere ibeere lọwọ ẹ, ṣugbọn ti wọn ni ko le dahun daadaa, paapaa to tun fẹ maa ba wọn ṣe agidi, eyi lo mu ki wọn yẹ gbogbo inu mọto naa wo, ti wọn si tun wo buutu ẹ.

Iyalẹnu lo jẹ pe oriṣiriṣi oogun abẹnugọngọ ni wọn ba ninu mọto SUV naa, ẹrọ kọmputa lagbeeka ti Apple.

 
Loju ẹsẹ la gbọ pe wọn ti wa Victor, ọmọ bibi ipinlẹ Ẹdo naa lọ si ileeṣẹ wọn, nibi ti wọn ti n ṣeadi ẹ lọwọ, ta a si gbọ pe wọn ko ni pẹ ẹ foju ẹ bale ẹjọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI